Dino Melaye Marriage Proposal: Se lóòtó ni sẹ́nátọ̀ Dino Melaye fẹ́ gbé ìyàwò tuntun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Wọ́n ni ọ̀ba kìí wà láì ni olòrì láàfin, sùgbọ́n kìí ṣe ọba aláde tó wà nípò nikan lọ̀rọ̀ yìí bá wí o.

Gbogbo ọkùnrin tó bá ti bàlágà, tó sí lé mu ọwọ́ lọ sẹnu láì woju olójú, náà ni ìyàwó yẹ kó wà lẹ́ẹ̀dẹ̀ rẹ̀.

Ó dàbí ẹni pé, èyí ni ọmọbinrin kan rí tó fi gbà láti di aya lọ́ọ̀dẹ̀ Dino Melaye, tii se gbájúgbaja ṣẹ́nétọ̀ tí àtúndi ìbò Kogi West yọọ kúrò nílé ìgbìmọ̀ asofin l'Abuja laipẹ yii.

Bí wákati díẹ̀ sẹyìn ni ìwé ìpè síbi wẹ̀jẹ-wẹ̀mu àti ayẹyẹ ìgbéyàwó Dino jẹyọ lórí ayélujara, níbi ti wọ́n ti ń pe àwọn ènìyàn sí ilé ìjọsin kan ni àgbègbè Ogudu nípìnlẹ̀ Eko.

Ninu iwe ipe sibi ase igbeyawo naa, ni aworan obinrin kan wa, ti orukọ rẹ n jẹ Susu, ẹni to pupa lawọ, to si rẹwa lobinrin.

Fọto Dino ati obinrin naa lo wa lara iwe ipe igbeyawo ọdun, ti wọn ni yoo waye ni ọjọ Satide, ọjọ keji ọdun Keresimesi, eyiun ọjọ kẹrindinlọgbọn osu Kejila ọdun 2020.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sé lóòtọ́ ni pé Dino fẹ́ ṣe ìgbeyàwó?

Dino Melaye gan ló ké gbàjare síta pé, àyínikè, àti àdàmọndi fọtọ ló jẹyọ lórí ayélujára nítori pé, òun kò mọ ọmọbinrin náà ri.

Ó ní " Báwó ni ń o ṣe ṣe ògbẹyàwó nígbà ti kò tíì san owó orí mi"

Bákan náà ló ké gbàjarè pé, ìwà gbajuẹ 419 ni èyí nítorí pé òun kò mọ obìnrin náà rí débi ti àwọn yóò maa sọ̀rọ̀ ìgbéyàwó.

O ní kóda kó ṣe fíìmú àgbéléwo, irú rẹ̀ kò le wáyé, ko si si ààyè l'ágàbá SDM.

ni àwọn ọmọ Nàìjíríà n sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí?

Bí àwọn kan ṣe ń kín ọmọbinrin náà lẹ́yìn pé kìí ṣe òní ni Dino Melaye ti mọ pé ọmọbinrin náà nífẹ̀ẹ́ Dino, tìí kìí sì fi pamọ lórí ayélujára, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn míràń sọ pé, ìgbésẹ̀ obìnrin náà kò bójúmu tó.

Bákan náà ni àwọn fótò míràn tó jẹ́ ti ọmọbinrin ọ̀hún àti Dino Melaye tún súyọ lórí ayélujara.