You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Risikat Azeez: Kaosarat àti Hassanat gba ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ₦1.5m ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́dún
Bi ori ba pẹ titi nilẹ, yoo pada di ire ni, ori ẹni si ni gbe alawore ko ni.
Ojo iranlọwọ to n rọ fun tọkọ taya Risikat ati Abdulwasiu Dada, ti iyawo rẹ jẹ oloju buluu ko tii dawọ duro.
Idi ni pe oore ọtun miran tun sẹsẹ wọle tọ idile naa ati awọn ọmọ wọn wa ni.
- Kí ló tún ṣe Òṣèré fíìmù Yorùbá míì tó ń gba ẹ̀jẹ̀ àtomi níléèwòsàn?
- Báyìí ni Àrẹ̀mọ Ooni Adeyeye Ogunwusi ṣe wọ ṣọ́ọ̀ṣì fún ìgbà àkọ́kọ́ láti bá bàbá rẹ̀ ṣe ìdúpẹ́ ìwúyè
- Wo ìdí tí ọmọ ọdún mẹ́wàá ṣe ti àbúrò rẹ̀ ọmọ ọdun kan àbọ̀ sínú kàǹga
- 'Ìdí tí a ò fi pa àwọn ajínigbé tó gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kankara nìyìí'
- Mo gbóríyìn fún Buhari bó ṣe dóòlà ẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé ní Kankara
- Aya gómìnà Kwara gba ilé fún Risikat olójú búlúù àti ọkọ rẹ̀
- Risikat, ìyá àwọn ọmọ olójú búlù tí bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́sẹ́ aṣojú lóge
- Báwo ni mo ṣe fẹ́ fi ìyàwó àfẹ́sọ́nà mi akáta hàn fáwọn òbí mi?
Bẹẹ ba gbagbe, iroyin gbalẹ ni osu kẹjọ ọdun 2020 nipa arabinrin Risikat, ti ọkọ rẹ Abdulwasiu le jade pẹlu ọmọdebinrin meji nitori pe tiya tọmọ ni oju buluu.
Ni kete ti iroyin naa jade sita, ni ọgọọrọ ọmọ Naijiria dide tako igbesẹ naa, ti aya gomina Kwara naa si da sọrọ wọn.
Lẹyin osu diẹ ti ọrọ naa ja rain-rain wọn pada so yigi fun tọkọ taya naa, ti aya gomina si gba ile fun wọn pẹlu silu Ilorin lati maa gbe.
Bakan naa ni aya gomina Kwara fi awọn ọmọdebinrin mejeeji naa sile iwe to jẹ ọkan lara awọn ile ẹkọ to dara julẹ ni ipinlẹ Kwara.
Orukọ awọn ọmọdebinrin oloju buluu naa ni Kaosara ati Hassanat Abdulwasiu.
Amọ akọtun oore to tun wọle tọ idile naa bayii ni ti ẹbun ẹkọ ọfẹ ti oludasilẹ ile iwe wọn fun awọn ọmọbinrin meji ti tọkọtaya Dada bi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àìmọ̀kan ló mú mi hu ìwà tí mo hù kọjá sẹ́yìn, Jonathan dárí jì mí - Dino Melaye
- Ẹ́ tú èékánná lọ́rùn Sowore, ẹ kò ní ẹ̀rí láti ba ṣẹjọ́ - Ẹgbẹ́ Amòfin Amẹ́ríkà
- Irú iṣẹ́ wo ní Funke Akindele rán sí Bukunmi Oluwasina, tó fa ariwo lórí ayélujára?
- "Buhari, o kò ṣe bẹbẹ kankan láì jẹ́ pé o gba Leah Sharibu náà sílẹ̀"
- Wo àwọn nǹkan to tún nílò NIN fún yàtọ̀ fún ìforúkọsílẹ̀ síìmù
- Ilé aṣòfin àgbà yọ gómìnà nípò, ẹni tó fi owó ìlú rán ọmọ lọ sí Amẹ́ríkà
- Amẹ́ríkà yarí pé àwọn agbégbọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ 344 gbọ́dọ̀ fojú winá òfin
Nigba to n fidi iroyin ayọ naa mulẹ fun BBC Yoruba, ọkọ iya Kaosara oloju buluu, Abdulwasiu ni lootọ ni oriire naa wọle ti idile oun.
O ni iyawo gomina Kwara lo mu awọn ọmọdebinrin naa lọ sile ẹkọ aladani Roemichs International School nilu Ilorin to jẹ olowo nla, eyi ti arabinrin Jumoke Harb da silẹ.
Gẹgẹ bi iroyin naa ti wi, Kaosara ati aburo rẹ wa lara awọn akẹkọọ mẹfa ti oludasilẹ ile ẹkọ naa, Harb fun ni ẹbun ẹkọ ọfẹ lọjọbọ lasiko ayẹyẹ opin ọdun.
Awọn akẹkọọ ile ẹkọ Roemichs yii ni wọn se idanwo fun lati figa gbaga, ki wọn le mọ akẹkọọ to pegede fun ẹbun ẹkọ ọfẹ naa, ti o to miliọnu kan abọ naira niye fun akẹkọọ kọọkan.
Lẹyin idanwo naa, akẹkọọ mẹrin lo yege lati janfaani eto ẹkọ ọfẹ naa nile ẹkọ girama ati ti alakọbẹrẹ to wa ninu ọgba ile ẹkọ naa
Owo yii si ni yoo gbọ bukata owo ileewe akẹkọọ naa, owo ilegbe, asọ ileewe ati awọn iwe ti wọn yoo lo fun ọdun kan.
Nibi ayẹyẹ fifunni lẹbun ẹkọ ọfẹ naa si ni Kọmisana feto ẹkọ nipinlẹ Kwara, Hajia Fatimah Ahmed bawọn peju si.
Ninu ọrọ rẹ, Ahmed wa sapejuwe ileẹkọ Roemichs gẹgẹ bii ile ẹkọ to wa lara awọn ibudo ikẹkọọ to ni akọsilẹ eto ẹkọ to pegedejulọ.
Baba Kaosara, ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba lori isẹlẹ yii fi ẹmi imoore rẹ han pupọ fun awọn eeyan to se idile naa laanu.
Abdulwasiu Dada wa se adura fun alaanu wọn, to fun awọn ọmọ rẹ mejeeji ni ẹbun ẹkọ ọfẹ naa pe Ọlọrun yoo tubọ maa mu ọwọ rẹ lọ siwaju.
Bakan naa lo gbadura fun aya gomina ipinlẹ Kwara to se alatọna oore naa, pe Ọba Oke yoo fun ni ẹmi gigun ati alaafia, ti wsn yoo si se aseye ti alakan n sepo lori oye.