You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dino Melaye pa àga dà, ó jókòó ságbo PDP
Ipinnu Sinetọ Dino Melaye lati lọ joko sẹba aga ti Sinetọ David Mark maa n joko si, ti n mu ki ọpọ ọmọ Naijiria maa beere pe, se sinetọ naa ti fi ẹgbẹ oselu APC silẹ ni, to si ti ba ẹgbẹ oselu PDP lọ ?
Awọn onwoye ni, boya igbesẹ yii ni Melaye fi n pasamọ fawọn ọmọ ilẹ yii pe, oun ti ba ẹgbẹ oselu PDP lọ.
Ohun to dabi ere ori itage naa bẹrẹ, nigba ti Dino Melaye rọ aarẹ ile asofin agba, Bukọla Saraki pe, ko pasẹ fun agbọpa ile pe, ko wa aaye fun oun ni agbo tawọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP maa n joko sii, to si ni oun fẹ jokoo si ẹba aarẹ ile tẹlẹ, Sinetọ David Mark.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Kia si ni awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP tete faa mọra, ti wọn si wa aaye fun laarin wọn, paapa lẹba aga David Mark bi o til jẹ pe Mark ko si lori ijokoo.
Amọ sa, Saraki pasẹ pe, ko si idi fun Melaye lati paarọ ijoko.
Bẹẹ ba si gbagbe, Òwúrọ̀ Ọjọ́rú ni Melaye padà sí ilé aṣòfin lẹ́yìn rògbòdìyàn tó wáyé láàrin rẹ àti àwọn ọlọ́pà, lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé, ó pa irọ́ pé àwọn kan fẹ́ gba ẹ̀mí òun, tó fi mọ̀ bí àwọn ọ̀daràn kan tí ọwọ́ tẹ̀ ṣe sọ pé, Melaye ni baba ìsàlẹ̀ àwọn.