You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Muhammadu Buhari: Femi Adesina tọ́ka sáwọn ẹ̀rí pé kìí ṣe ẹ̀dà ààrẹ ló ń darí Nàíjíríà
Kii se ohun tun mọ pe ki asaaju ikọ IPOB, Nnamdi Kanu ati awọn ọmọ Naijiria kan maa pe aarẹ orilẹede yii, Muhammadu Buhari ni ẹda eniyan.
Koda wọn ni kii se Buhari ti awọn dibo fun lo wa lori aleefa amọ o ti ku lasiko to se aisan, to si lọ gba iwosan nilu London lọdun 2017.
Kanu ni wọn ti fi ọkunrin kan, to pe orukọ rẹ ni Jubril lati orilẹede Sudan, rọpo aarẹ Naijiria to ni o ti di oloogbe ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ dín agbára ìjọba àpapọ̀ kù, kẹ ṣì ṣe àgbékalẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ - Tinubu bẹ̀bẹ̀
- Wo eyi to súnmọ́ ọ nínú àwọn ibùdó 203 fún ìforúkọsílẹ̀ fún NIN rẹ
- Adigunjalè méjì ko ìjàmbá ọ̀kadà lẹ́yìn ìṣẹ́ ibi n‘Ibadan, ọ̀kan kú lójijì, aráàlú dáná sun èkejì
- Àwọn ohun kàyéèfì tó le mú kí ọmọbìnrin ní oyún ìju
- Ìrẹ̀sì kò gbọdọ̀ wọlé níbáyìí ta ṣí ẹnu bodè padà - Ìjọba àpapọ̀
- Jide Kosoko forin sẹ́nu pé òun ni igi lẹ́yìn ọgbà Mr Latin lórí ipò ààrẹ TAMPAN tó wà
- Ó pé ọdún mẹ́wàá tí Barrister kú; wo ǹkan tó yẹ láti mọ̀ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olórin, tẹ̀wé-tẹ̀wé, akọ̀wé àti sọ́jà
- Àìmọ̀kan ló mú mi hu ìwà tí mo hù kọjá sẹ́yìn, Jonathan dárí jì mí - Dino Melaye
Koda Kanu fi ọwọ sọya pe, oun ni awọn ẹri aworan to daju lọwọ lati fidi rẹ mulẹ pe, ẹlomiran lo n dari ijọba Naijiria, kii se Buhari.
Sugbọn niwọn igba to se pe isọrọ ni igbesi, idi ree ti olugbanimọran fun aarẹ lori eto iroyin, Femi Adesina fi bọ sita lati sọrọ nipa iroyin to n ja rainrain nilẹ naa.
Adesina, ninu ọrọ kan to kọ ni ayajọ ọjọ ibi ọdun kejidinlọgọrin aarẹ Muhammadu Buhari salaye pe, aarẹ kii se ẹda rara, oun gan si ni, wọn ko fi ẹlomiran se rara.
Amugbalẹgbẹ fun aarẹ, ẹni to foju laifi wo ọrọ ti Kanu n gbe kiri yii, tun se apejuwe ọrọ naa bii ero awọn omugọ, eyi ti ọpọ ọlọgbọn gan tun n gba a gbọ pẹlu.
Femi Adesina wa tọkasi awọn ẹri kan to fidi rẹ mulẹ pe wọn ko fi ẹlomiran rọpo aarẹ Buhari rara, oun fura rẹ lo n dari ijba Naijiria.
"Ni ọjọ ti aarẹ gunlẹ sorilẹede Naijiria lati London to ti lọ gba iwosan, ọjọ naa ni olori ẹka alaabo ilẹ wa, Ọgagun Abayomi Olonisakin n fi ọmọbinrin rẹ lọkọ.
Mo wọ agbada ati fila, tii se asọ ibilẹ wa lọ sibi igbeyawo naa, nibẹ si ni mo ti lọ pade aarẹ Buhari ni papakọ ofurufu.
Gbogbo wa to lori ila lati ki aarẹ kaabọ, ti oun naa si n bọ wa lọwọ ni ẹyọ kọọkan, nigba to de iwaju mi lo ni 'Adesina, igba yii ni maa ri ẹ fun igba akọkọ to wọ asọ to dara julọ'."
Adesina ni awọn mejeeji ku silẹ fun ẹrin, tawọn ayaworan si ya awọn, eyi ti wọn lo lori mohunmaworan, ti ọpọ eeyan si n bi ohun leere pe ki lo mu ki awọn mejeeji rẹrin arintakiti bẹẹ.
Adesina wa n bi awọn eeyan to n siyemeji nipa Buhari pe "Se ti kii ba se aarẹ lo n ba oun sọrọ, bawo ni yoo se mọ orukọ oun, ti yoo si tun mọ pe oun kii saba wọ asọ agbada?"
Bakan naa ni Adesina mu wa si iranti pe akọroyin kan wa, Lindasay Barret to jẹ ọrẹ ọlọjọ pipẹ fun Buhari, to si ran oun lati ki aarẹ fun oun.
O ni bi oun se n fi isẹ ikinni Barret jẹ fun aarẹ Buhari lo fesi pada pe "Lindasay Barret, mo ranti pe emi ati ẹ pade loju ogun lọdun 1968.
"Se to ba jẹ Jubril ti Sudan ni, se yoo ranti ọrẹ rẹ ati ibi ti wọn ti pade loju ogun lọdun 1968, ẹ gbe irọ da sọhun, ko jẹ wa."
Amugbalẹgbẹ fun aarẹ wa kadi ọrọ rẹ nilẹ pe ololufẹ Naijiria ni aarẹ Muhammadu Buhari, ti oun si mọ ọbuda ati isẹ rere rẹ daradara.