Yoruba Nollywood: Jide Kosoko ní Mr Latin ò lè dá a ṣe gẹ́gẹ́ bí ààrẹ TAMPAN

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba Jide Kosoko ti ni oun wa lara awọn to jẹ igi lẹyin ọgba fun aarẹ ẹgbẹ TAMPAN, Bolaji Amusan ti gbogbo eeyan mọ si Mr Latin.

Eyi waye nibi ipade apero ẹgbẹ awọn oṣere Yoruba to n jẹ TAMPAN ni ilu Ibadan olu ilu ipinlẹ Oyo.

Ipade naa lo ko ọpọlọpọ ọdọ ati awọn agbaagba oṣere Yoruba jọ lati jiroro lori ọna ti ẹgbẹ naa yoo fi tẹsiwaju.

Ninu fidio ati awọn aworan ti aarẹ ẹgbẹ naa fi sita ti o kọ akọle si pe ipade idanilẹkọ naa jẹ aṣeyọri.

Bo tilẹ jẹ pe iṣẹ wọn ni lati da awọn eeyan lara ya, akoko naa tun pese anfani lati wo ere idaraya funrawọn.

Lasiko ti wọn n kadii eto naa nilẹ ti awọn agbaagba jọ wa laarin ara wọn ni Jide Kosoko fi ẹrọ gbohungbohun kọ ọrọ rẹ lorin pe "... ṣugbọn Latin o le da a ṣe o, awa ni igi lẹyin ọgba rẹ".

Ṣe ni gbogbo awọn to wa nibẹ wo o latẹwọ ti agba oṣere mii, Adebayo Salami ti ọpọ mọ si Ọga Bello sọrọ pe yoo sọ itumọ orin to kọ toripe ko ye oun to.

Ọga Bello sọ fun Mr Latin to jẹ aarẹ pe Ọlọrun ọba to baa bẹrẹ naa ni ko maa gbe oju le ko ma ṣe gba gbọyi sọyii to maa n jẹ jade latọdọ awọn akẹgbẹ wọn.

Lara awọn gbajumọ oṣere to wa nibi akọja ewe ipade idanilẹkọ naa ni Mr Latin, ọga Bello, Jide Kosoko, Yinka Quadri.

Awọn mii to wa nib nini Damola Olatunji, Sola Kosoko, Odunlade Adekola, Femi Adebayo Salami, Muyiwa Ademola ati awọn to ku.