Yollywood: Odunlade Adekola àtàwọn òṣèré sinimá Yorùbá míràn tó padà lọ sí fásiti lọ kàwé

Ọpọ lo n ri awọn eekan ilu, paapaa awọn oṣere sinima gẹ¶gẹ bi awọn to ti ni gbogbo ohun ti wọn n fẹ tan.

Amọṣa, diẹ ninu wọn ni ọwọ awọn ko tii tẹ eku ida eto ẹkọ nitori naa awọn n pada lọ si ile ẹkọ lati lọ kẹkọ.

Diẹ niyi lara awọn oṣere tiata Yoruba to ti pada ls kawe gboye ijinlẹ lẹyin ti wọn bẹrẹ ere sinima ṣiṣe:

Ọdunlade Adekọla

Gbajumọ ni Ọdunlade adekọla ninu ka ṣe ere tiata Yoruba, koda o ti gbiyanju ninu awọn sinima miran to jẹ ti ede oyinbo pẹlu. Gbogbo aye lo si n fẹran rẹ eleyi ti o farahan ninu awọn ami ẹyẹ to ti n gba nihin ati lọhun.

Ọmọ ilu Ọtun Ekiti ni ipinlẹ Ekiti ni, ṣugbọn Abẹokuta lo gbe dagba, eyi ti o si maa n fi han ninu ede ẹgbọ ti o maa n saba lo ninu ere rẹ nigba miran.

Ni ọdun 1996 ni ọdunlade Adekọla bẹrẹ ere tiata ṣiṣe, ni ọdun 2018 ni Ọdunlade Adekọla kẹkọ gboye ijinlẹ ninu imọ akoso okoowo, (Business Administration) ni fasiti ilu Eko, Unilag.

O ni igbagbọ oun ninu wiwa imọ kun imọ lo ṣokunfa bi oun ṣe pada si ileewe.

Muyiwa Ademọla

Sinima 'Ori'lo fọnrere Muyiwa Ademọla, ti ọpọ ṣaaju mọ si Muyiwa Authentic, sita.

Ni ọdun 2006 lo pada si fasiti ilu Ibadan lati lọ kẹkọ Diploma nipa imọ ẹkọ agba ati idagbasoke agbegbe, (Diploma in Adult Education and Community Development)

Ọlanrewaju Omiyinka (Baba Ijeṣa)

Baba Ijeṣa kii ṣe alejo ni agbo ere sinima, paapaa julọ sinima ede Yoruba. O si jẹ ọkan lara awọn adẹrinpoṣonu ninu ọpọlọpọ ere.

Fasiti ilu Eko ni baba Ijeṣa pada lọ lati lọ kawe gba ims nipa ere tiata. O ni oun ṣe bẹẹ lati lee tubọ jawe sobi irinajo oun nile aye ni.

Bọlaji Amusan (Mr. Latin)

Lẹyin ọdun marundinlogoji to pari ẹks girama ni Bọlaji Amusṣan ti ọpọ mọ si Mr. Latin pada si ileewe giga. Faisiti agbelegboye ti orilẹede Naijiria, National Open University lo si lọ lati lọ kọ nipa eto alaafia ati ipẹtu si aawọ