Otedola Estate rèé níbí tí ọkọ̀ aképo ti gbiná l'Eko

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Titi di alẹ ọjọ Abamẹta ni awọn oṣiṣẹ panapana fi n gbiyanju lati dawọ ina to n ran latara ọkọ akepo kan to n jona lẹba agbegbe Otedola Estate nipinlẹ Eko to wa lopopona Eko si Ibadan.

Fidio to tan kalẹ kaakiri oju opo ayelujara fihan bi eefi kiki ṣe n ru soke to si di gbogbo oju awọsanmọ lasiko ti awọn ọkọ n kọja eyi to ti bẹrẹ lati nkan bii ago mẹfa kọja nirọlẹ.

Eyi mu ki awọn wọ lọ si ọna ibomii lati gba.

Agabegbe Otedola Estate yii ko ṣajoji si ijamba ina oniruuru gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe n figbe ta pe afara Otedola nilo itusilẹ tabi atunṣe awọn akọṣẹmọṣẹ.

Laipẹ ninu oṣu kẹwaa ọdun yii kan naa ni ọkọ kan to kun fọfọ fun epo gbina lorii afara Otedola.

Ṣe ni ina naa jo titi di alẹ ti awọn oṣiṣẹ panapana ati awọn oṣiṣẹ ajọ pajawiri ṣi n gbiyanju lati ri i pe ko pa eniyan lara.

Amọ gẹgẹ bi ọga ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA, Olufemi Oke-Osanyintolu ṣe sọ, ko si mi to ṣofo ninu ijamba eyi to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ yii amọ nkan ini to bajẹ ko tii lonka.