Majeobaje: Gómìnà, ẹ gbé owó ńlá fún Amotekun kó le dábírà lẹ́ka ètò ààbò

Ẹgbẹ kan to jẹ ti ọmọ bibi ilẹ Yoruba, Majeobaje ti ke sawọn gomina lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria lati wa ojutu si ipenija eto aabo.

Bakan naa ni wọn woye pe awọn gomina nilẹ Kaarọ oojire to wa ni Eko, Oyo, Osun,Ogun,Ekiti ati Ondo ti kuna ninu ojuse wọn lati pese aabo to jiire silẹ Yoruba.

Atẹjade kan ti akọle rẹ n jẹ 'ẹ gba ẹmi wa la', ti ẹgbẹ Majeobaje naa kọ si gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, tii se alaga awọn gomina lẹkun yii, lo sisọ loju ọrọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade naa, ti wọn fi ẹda rẹ sọwọ sawọn gomina yoku nilẹ Kaaro Oojire, wa kọminu lori iwa ipaniyan, ijinigbe, ifipabanilopọ atawọn iwa ọdaran mii, to n gogo nilẹ Yoruba.

Ẹgbẹ Majeobaje wa n kọminu lori idi ti ikọ Amotekun ko se tii bẹrẹ isẹ to jọju nidi idaabo bo ẹmi ati dukia nilẹ Yoruba, gẹgẹ bi awọn araalu ti n foju sọna fun.

"Awọn janduku agbebọn ti gba ẹkun ariwa Naijiria kan, Awọn Fulani darandaran n sa fun asalẹ, awọn eeyan to n fori sọta ọsẹ Boko Haram n wa aabo.

Bẹẹ si ni awọn ọdọ ti ko ri isẹ se n wa isẹ kiri gbogbo ẹkun to wa ni Naijiria, ẹkun iwọ oorun guusu si ni gbogbo awọn eeyan ta mẹnuba yii n sa wa.'

Titara titara si ni wọn n rin pẹlu ibọn Ak47, ti wọn si n fi ipa aba awọn obinrin wa lopọ, bẹẹ ni wsn n gbẹmi eeyan laibikita, koda, wsn ko tun bọwọ fun ẹmi eeyan, asa ati ofin pẹlu."

Ẹgbẹ Majeobaje wa rọ awọn gomina nilẹ Yoruba lati gbe owo kalẹ fun ikọ Amotekun, ki wọn si gba osisẹ to to sibẹ, ki wọn lee wa laarin ilu ati igberiko gbogbo.

Ẹgbẹ naa ni ti awọn gomina ilẹ Kaarọ Oojire ko ba san sokoto wọn ko le lati se ohun to tọ nidi didaabo bo araalu, awọn araalu le pinnu lati maa se ohun to ba wu wọn lati daabo bo ẹmi ati dukia wọn.

Ṣé lọ́òtọ́ ni ọlọ́pàá dàwátì torí àti dóòlà ọmọ India méjì tí wọ́n jígbé?

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fi hande pe lootọ ni awọn ajinigbe ji ọmọ orilẹede India meji ni ipinlẹ Oyo.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi sọ fun BBC Yoruba pe awọn n ṣe akitiyan lati doola wọn ki wọn si fi panpẹ ofin mu awọn kọlọransi ẹda to ji wọn gbe ọhun.

Ẹwẹ nigba ti akọroyin bere boya lootọ ni wọn tun ji awọn ọlọpaa gbe nigba ti wọn n gbiyanju lati doola awọn ọmọ orilẹede India ọhun, alukoro ọlọpaa ni oun lee sọ dajudaju pe irọ ni.

Olugbenga ni ko si ọlọpaa kankan ni ipinlẹ Oyo to farapa tabi ti wọn jigbe nitori iṣẹlẹ yii. O ni ọgbọn awọn oniwa aburu ẹda lati tẹmbẹluu agbara ọlọpaa nipinlẹ Oyo ni.

Torinaa, ileeṣẹ ọlọpaa ni awn eeyan awọn ti kan si agbami iṣẹ fun itusilẹ awọn ọmọ India naa ti wọn jigbe ni ile ita ogun kan lagbegbe Toll Gate ni opopona Eko si Ibadan ni nkan bii ago mẹrin irọlẹ.

"Opopona Eko si Ibadan ni wọn ti ji wọn gbe l'Ọjọru ọsẹ awọn eeyan wa si n ṣiṣẹ takun takun lati doola wọn pada ki wn lee wa pọ pẹlu ẹbi wọn" Eyi ni alukoro ọlọpaa Oyo sọ.

Awọn mejeeji la gbọ pe awọn ajinigbe da lọna lasiko ti wọn n wa ọkọ jade ninu ọgba ile itaja ogun naa.