You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Omah Lay àti Tems yóò tó darí padà sí Nàìjíríà
Ijọba orilẹede Naijiria ti fi aridaju han pe awọn olorin ọmọ Naijria meji ti orilede Uganda fẹsun kan, Omah Lay ati Tems yoo to dari wale.
Oludari ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ́ Naijiria to wa nilẹ okere, Abike Dabiri-Erewa sọ fun ileeṣẹ BBC lọjọ Iṣẹgun ọsẹ pe orilẹede Uganda ti jawọ ninu ẹsun ti wọn fi kan wọn lẹyin ọjọ kan tawọn olorin yii farahan niwaju ile ẹjọ majisireeti Uganda.
Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Uganda fi ẹsun kan Stanley Omah Didia ti inagijẹ rẹ jẹ Omah Lay, Temilade Openiyi to n jẹ Tems ati ọmọ Naijiria kan, Muyiwa Awoniyi pe wọn n mọọmọ ṣe ohun to lee pin arun to lee ran ka kiri.
Olorin ọmọ orilẹede Uganda, Bebe Cool fi aworan iwe ile ẹjọ ti wọn fi paṣẹ pe ki wọn tu awọn mẹtẹẹta silẹ sita loju opo Twitter.
Iwe naa lo ṣafihan pe inu gba ẹwọn kan ni Kigo ni wọn gbe wọn ju si.
Bakan naa, kan lara awọn oludije ipo aarẹ ni Uganda toun naa jẹ olorin, Bobi Wine ni agbẹjọro oun darapọ mọ wn ninu akitiyan lati dawọ ẹjọ ti wọn n pe lori awọn olorin ọmọ Naijiria yii duro to si ni inu oun dun bo ṣe ṣẹlẹ
Ki ni awọn Naijiria n sọ lori bi ijọba ṣe ran Omah atawọn to ku rẹ lọwọ?
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria to fi mọ awn oloṣelu lo n funpe si ijọba pe ki wn tete ba ijọba orilẹede uganda sọrọ ki Omah Lay atawọn to ku rẹ ma baa pẹ lẹwọn.
Nitori naa nigbati iroyin itusilẹ wọn bọ ode, ọpọ lo tu sori ayelujara lati dupẹ lọwọ gbogbo awọn to kẹnu bọ ọrọ naa ati bi ijọba Naijiria ko ṣe fa sẹyin rara lori ọrọ naa.
Bí olórin ọmọ Nàìjíríà, Omah Lay se dèrò ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Uganda
Adajọ kan ni Uganda ti ni ki wọn fi olorin ọmọ Naijiria, Omah Lay, Temilade Openyi, ti ọpọ mọ si Tems ati Muyiwa Awomiyi si ọgba ẹgba ẹwọn di Ọjọru.
O ni ki wọn fi Omah Lay si ẹwọn to wa ni Kitalya, nigba ti Tems yoo wa ni ẹwọn Kigo.
Wọn fi ẹsun kan Omah Lay atawọn ẹmẹwa rẹ nile ẹjọ majistrati Makidye pe wọn mọọmọ wu iwa to le mu ki arun Covid-19 burẹkẹ si lorilẹ-ede naa.
Ọpọ awọn ololufẹ olorin naa ni Najiria lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ẹsun ti wọn fi kan an, ti awọn mii si sọ pe ejo lọwọ ninu.
Omah Lay ti fojú balé ẹjọ́ ní Uganda
Ileeṣẹ ọlọpaa Uganda ti gbe olorin takasufe ọmọ Naijiria, Stanle Didia, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Omah Lay atawọn meji miran lọ sile ẹjọ.
Ileeṣẹ naa lo fi ikede naa sita loju opo Twitter rẹ lọjọ Aje.
Wọn ni "awọn ọmọ Naijiria mẹta, Stanle Didia, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Omah Lay, Temilade Openiyi, ti ọpọ mọ si Tems, ati Muyiwa Awoniyi ti foju bale ẹjọ."
Atẹjade naa tẹsiwaju pe ẹsun ti awọn eeyan naa n jẹjọ le lori ni titapa si ofin to rọ mọ ilana ajakalẹ arun Covid-19.
Ṣaaju ni ileeṣe naa ti kọkọ ka jale lati ga beeli wọn lẹyin ti wọn ni iwa ti wọn wu le yọri si iburẹkẹ arun naa lorilẹ-ede ọhun.
Iléesẹ́ ọlọ́pàá Uganda mú akọrin Naijiria, Omah Lay fún rírú òfin ìlànà Covid-19
Ileesẹ ọlọpaa orilẹ-ede Uganda ti mu gbajugbaja akọrin takasufe, to jẹ ọmọ Naijiria, Omah Lay, ati awọn eeyan meji mii, fun titapa si ilana Covid-19.
Ileesẹ ọlọpaa Uganda fi iroyin naa mulẹ, ninu atẹjade kan ti alukoro rẹ, SP Patrick Onyango, fi sita lọjọ Aiku.
O ni "eeyan mẹta ni ọwọ wa ti tẹ, fun pe wọn lọwọ si ipago orin ita gbangba, ni Ddungu Resort, ni ilu Kampala, lọjọ Satide.
" Awọn ti ọwọ wa tẹ ni alamojuto ibudo naa, Ivan Ddungu, Omay Lay, ati alamojuto eto naa to pe Omay Lay sibi ariya naa, Prim Kasana.
Omay Lay fúnra rẹ sọ pe otitọ ni iroyin naa, loju opo ayelujara Twitter rẹ.
Ileesẹ ọlọpaa kọkọ sọ pe awọn n wa alamojuto ileesẹ ọlọpaa ni agbegbe naa, nitori pe o kuna pe 'ko mọ' nipa iwa ọdaran to n waye ni agbegbe rẹ.
Ọwọ si ti pada tẹ ọlọpaa mẹta, fun pe wọn pa imọ pọ pẹlu awọn to ṣeto ariya naa, lati pese aabo nibẹ.
Yatọ si eyi, wọn ni ọwọ àwọn tun ti pada tẹ akọrin obinrin ti oun na jẹ ọmọ Naijiria, Temilade Openiyi 'Tems', fun ẹsun kan náà.
O fi fidio nipa ariya naa sita lọjọ Satide.
Awọn ọlọpaa sọ pe apejẹ ọsan àti alẹ ni awọn awọn to ṣe agbatẹru ariya naa sọ pe awọn n ṣe, sugbọn wọn bẹrẹ si ni pe awọn olorin wọle ni alẹ.
"Awọn afurasi naa ti wa ni ileesẹ ọlọpaa Katwe, ẹsun iwa to le mu ki aarun Covid-19 pọ si lao si fi kan wọn".
"Nitori pe, ni ibẹrẹ itankalẹ coronavirus, ni aarẹ ti pàṣẹ pe ki opin o deba ariya orin ita gbangba. Àṣẹ naa si wa sibẹ.
" A koro oju si iwa àwọn onimọtara ẹni nikan, to fi ẹ̀mí ọpọlọpọ ọmọ orilẹ-ede Uganda sinu ewu, nitori pe wọn n wa owo."
Iroyin sọ pe agbenusọ ileesẹ ọlọpaa ni ẹkùn Kampala, Luke Owoyesigyire ní o se e ṣe ki wọn o ṣe ayẹwo aarun Covid-19 fun awọn afurasi naa.
"Ti esi ayẹwo ba fi han pe wọn ni i, ohun lao fi ṣe ẹri nile ẹjọ."
Àmọ́ ṣa, awọn ololufẹ Omah Lay ti n faraya lori ayelujara, ti wọn si n fi #freeOmahLay beere fun itusilẹ rẹ.