You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ondo politics: Ilé ẹjọ́ da ìpèjọ́ pé Akeredolu kọ ló wọlé ìdìbò ìpińlẹ̀ Ondo nù
Ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìlú Abuja ti da ẹjọ́ to ní Gómìnà Oluwarotimi Akeredolu kọ́ ló wọlé gẹ́gẹ́ bii gomina lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress (APC) nínú ìdìbò gómìnà tó wáyé nípìnlẹ̀ Ondo.
Adajọ́ Okon Abang nínú ìdájọ rẹ̀ lọ́jọ́rú ni ó ti kọ́ja ọjọ́ mẹ́rìnlá kí olùpẹ̀jọ́ to mu ẹjọ́ wá silé ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bi abala iwé òfin 285(9) ṣe làá silẹ̀ lórí ẹjọ to bá níṣe pẹ̀lú ìdìbò.
Olùpẹjọ́ ni olùdíje dùpò gómìnà míràn lábẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC Nathaniel Adijutelegan tó díje pẹ̀lu Akeredolu lásìkò ìdìbò abẹ́lé láti yan ẹni ti yóò dupò gómìnà nínú ẹgbẹ́ náà.
Ó pe ẹgbẹ́ lẹ́jọ́ fún irú ìlànà ti ó tẹ̀lé láti dìbò yan olùdíje dupò gómìnà lábẹ́ àsíà ẹgbẹ́ òṣèlú APC nípìnlẹ̀ Ondo.
Abang ni, ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáye láti ọjọ kẹtàdínlógún, oṣu kèje ọdún 2020 lásìkò tí wọ́n yan gómìnà ìpinlẹ̀ Kogi Yahaya Bello gẹ́gẹ́ bii alága ètò ìdìbò abẹ́lé náà, tí wọ́n sì gbà láti dìbò ní ọ̀nà tí kìí ṣe ìdìbò olójúkorojú, ọjọ́ kéta, oṣù kéjó, ọdún 2020 ni Adojutelegan ṣẹ̀ṣẹ̀ pe ẹjọ́.
Bákan náà ni ilé ẹjọ tún fi kún-un pé àwọn ẹsùn míràn tó wà nibẹ̀ kìí ṣe ǹkan ti ó kan ilé ẹjọ́ bíkòṣe ǹkan ti wọ́n yóò lọ yanju láàrin ara wọn ninu ẹgbẹ́, nítori náà ó da ẹjọ́ ọhun sígbó.
Ohun to kọkọ ṣẹlẹ ti iléẹjọ́ fi fk dájọ́ bóyá Gómìnà Akeredolu yẹ láti du ipò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ondo
Nigba ti wọn kọkọ pe ẹjọ naa, o dabii pe ọrọ ko tii tan fun Akeredolu, gomina ipinlẹ Ondo lẹyin ọpọlọpọ ọsẹ ti eto idibo gomina ipinlẹ Ondo ti gbee wọle fun saa keji.
Yatọ si pe alatako rẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Eyitayọ Jẹgẹdẹ n pe ẹjọ kotẹmilọrun ta ko o nile ẹjọ bayii lori esi idibo naa, ogun abẹle naa n ba Akeredolu finra pẹlu bii ọkan lara awsn ti wọn jijọ dije fun aṣia ẹgbẹ oṣelu APC fun idibo gomina naa,
Ọmọwe Nathaniel Adojutẹlẹgan ti pe e lẹjọ nile ẹjọ giga apapọ kan nilu Abuja pe ọna ti wọn fi yan an lati di aṣia ẹgbẹ naa ko ba ofin mu ati pe o tako ilakalẹ ofin idibo apapọ ilẹẹwa, Electoral Acts tọdun 2010.
Ọmọwe Adojutẹlẹgan n fapajanu pe iwe oruks awọn aṣojudibo ti wọn lo lasiko idibo abẹlẹ ẹgbẹ oṣelu naa ti wọn ti yan Akeredolu lati dije lorukọ ẹgbẹ oṣelu naa tako abala ikẹtadinlaadọrun iwe ofin idibo orilẹede Naijiria naa ati iwe ofin ẹgbẹ oṣelu APC.
Loni ọjọ kẹrinla oṣu kejila ọdun 2020 ni onidajọ Okon Abang to n gbọ ẹjọ naa ya sọtọ fun idajọ rẹ.
Ni ọjọ kẹta oṣu kẹjọ ọdun 2020 ni idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC fun awọn oludije ipo gomina nipinlẹ Ondo waye ti Akeredolu si bori.