Marwa NDLEA: Ta ni Mohammad Buba Marwa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀gá àgbà àjọ NDLEA?

Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Mohammad Buba Marwa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀gá àgbà àjọ NDLEA.

Mohammad Buba Marwa ni ọga agba tuntun ti ìjọba apapọ ṣẹṣẹ Yan fún ajo to n gbogun ti lilo egbogi oloro ni Naijiria, NDLEA.

Nigba to bẹrẹ iṣẹ ni ọọfisi rẹ tuntun, lọjọ Aje, o ni o jẹ ohun tó n kọ òun lominu pe pupọ nínú àwọn ọdọ Naijiria lo n lo egbogi oloro.

Marwa sọ pé "nnkan bíi 14.1 mílíọ̀nù ọmọ Naijiria lo n lo oriṣiriṣi oogun oloro."

Gẹgẹ bó ṣe sọ, iye ọjọ orí awọn tó n lo oogun náà jẹ láti ọdún marundinlogun sí mẹrinlelọgọta, lẹyin naa ló ṣèlérí pé adinku yóò dé bá iye èèyàn náà labẹ idari ohun.

Ta ni Mohammad Buba Marwa?

Wọn bí Mohammad Buba Marwa ni ọjọ kẹsán án, oṣù Kẹsán án, ọdún 1953.

O wa lati ìjọba ìbílẹ̀ Michika, ni ipinlẹ Adamawa.

Buba Marwa kawe ni ile ẹkọ awọn ologun to wa ni Zaria, nipinlẹ Kaduna.

Lẹyin naa ló tẹkọ leti lọ sí Pittsburgh, nibi to ti kọ ẹkọ nipa ìmọ ibaṣepọ laarin awọn orilẹ-ede, ko to gboye síi nipa ìmọ eto ìlú ní Fasiti Harvard.

Awọn ibi to ti ṣiṣẹ sẹyin:

O ṣiṣe gẹgẹ bíi gomina ipinlẹ Bornu labẹ ijoba ologun lọdun 1992, ìyẹn nigba ti ọgagun Ibrahim Babangida jẹ Ààrẹ.

Òun tun ni gomina ipinlẹ Eko lọdun 1996 nigba ti ọgagun Sani Abacha jẹ Ààrẹ ologun.

Ni 2003, Marwa fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bíi alaga àti Olùdarí ileeṣẹ ọkọ ofurufu Albarka Airlines.

Loṣu Kejìlá ọdún 2006, o kede pe òun fẹ du ipo ààrẹ labẹ àsìá ẹgbẹ òṣèlú PDP, ṣugbọn o fìdí janlẹ, èyí tó mú kó ṣegbe lẹyin Umaru Musa Yar'Adua to padà di Ààrẹ.

Ni 2007, Marwa di aṣojú Naijiria sí orilẹ-ede South Africa.

Lọdun 2011 o gbe àpótí ipo gomina labẹ àsìá ẹgbẹ Congress for Progressive Change, CPC, nipinlẹ Adamawa, ṣugbọn o tun fidi janlẹ.

Lẹyin-o-rẹyin, Marwa darapọ mọ ẹgbẹ òṣèlú APC lọdun 2015 lẹyin tí wọn búrawọle fún Ààrẹ Muhamadu Buhari.