Covid-19 vaccine in Nigeria: Abẹ́rẹ́ àjẹsára yóò wọ Naijiria láìpẹ́

Ìjọba àpapọ̀ gbé ₦10b kalẹ̀ fún ìpèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 alábẹ́lé

Covid-19 vaccine in Nigeria: Abẹ́rẹ́ àjẹsára yóò wọ Naijiria láìpẹ́

Minisita eto ìlera, Osagie Ehanire ti sọ pé ìjọba àpapọ̀ ti gbe biliọnu mẹwaa naira kalẹ fún ìpèsè abẹrẹ ajẹsara labẹle.

Osagie ni Naijiria ti n ba awọn tó n po oogun náà sọrọ lori ìpèsè rẹ.

Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ nipa abala akọkọ abẹrẹ ajẹsara ti wọn yóò kó wọ Naijiria laipẹ ree.

Awọn ọmọ Naijiria ti yóò kọkọ gbà abẹrẹ ọhún ti ileeṣẹ Pfizer-BioNTech ṣe yóò gba abẹrẹ náà ni oṣù kẹta, ọdún 2021.

Ìparí oṣù Kejì ni ìjọba gbagbọ sọ pe ẹgbẹrun lọna ọgọrun abẹrẹ náà yóò balẹ sí Naijiria.

Awọn wo ni abẹrẹ náà yóò kan?

- Awọn oṣiṣẹ eto ìlera

- Awọn adari to ṣe pataki

- Awọn ti iṣẹ wọn ṣe pàtàkì bíi àwọn òṣìṣẹ́ ni papakọ ofurufu

- Awọn ọlọpaa kan at'awọn aṣobode

- Awọn oṣiṣẹ ile iwosan ti wọn ti n ṣe ayẹwo Covid-19

- Awọn àgbàlagbà tó ti pé aadọta ọdún sókè

Ijoba apapọ ti sọ pé ọfẹ ni abala akọkọ abẹrẹ náà yóò jẹ fún àwọn ọmọ Naijiria.

Ẹwẹ, ìjọba àpapọ̀ tun ti n ba ileeṣẹ kan ni China jíròrò lórí bí wọn yóò ṣe kó mílíọ̀nù mejilelogoji abẹrẹ miran wọlé.