Ondo robbers vs Army attack: Adigunjalẹ̀ kolu sójà ní Ondo, wọ́n yìnbọn lú wọ́n ní àyà àti ní apá

Awọn adigunjalẹ ti ṣekọlu si awọn ikọ ọmọogun nipinlẹ Ondo.

Eyi waye lasiko ti awọn ọmọogun naa wa lẹnu iṣẹ ti wọn ni opopona Owo-Ifon, nipinlẹ Ondo.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa,Tee-Leo Ikoro to fi idi ọrọ naa mulẹ ni iṣẹlẹ naa waye ni Ọjọ Eti.

''Ẹnu iṣẹ ni awọn ọmọogun naa wa nigba ti wọn wa ọkọ de ibi ti awọn ole naa ti n ṣọṣẹ''

''Awọn ole naa yinbọn mọ ọkọ awọn soja naa, ti ibọn si ba ọkan ni aya, ekeji ni apa''

''Lẹyin yii ni wọn sa lọ sinu igbo, ti wọn si fi awọn eniyan ti wọn n ja lole lọ''

Agbẹnuṣọ ileeṣẹ ọlọpaa naa ni awọn ọmọogun to farapa naa ti wa ni ileewosan ijọba apapọ, Federal Medical Centre, Owo.

Ọlọ́pàá àti sọ́jà kó sí akóló ọlọ́pàá l'Ondo lórí ẹ̀sùn ìdigunjalẹ̀

Sọja ati ọlọpaa kọnsitebu kan to ṣẹṣẹ wọ iṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, David Friday ti wa ni akolo awọn agbofinro bayii lori ẹsun idigunjale.

Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Ondo sọ pe ọlọpaa naa ti kọkọ ji alupupu (ọkada) kan gbe tẹlẹ lago ọlọpaa to ti n ṣiṣẹ.

Agọ ọlọpaa to wa ni Olofin ni ijọba ibilẹ Idanre ipinlẹ Ondo ni Friday ti n ṣiṣẹ ki aje iwa ibajẹ naa to ṣi mọọ lori.

Sọja to jẹ ọkan lara wọn afurasi ti wọn fẹsun idigunjale ọhun kan, Innocent Victor n ṣiṣẹ pẹlu barake awọn ologun Naijiria, 32 Artillery Brigade, to wa ni Owena.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn di ọbẹ atawọn ohun elo ija mii mọra lorita Ojadale nibi ti wọn ti wọn ṣe ikọlu fawọn eeyan ti wọn si tun ja wọn lole.

Ẹrọ ibanisọrọ Itel ti wọn n ta ni N8500, epo bẹntiro jẹrika ọgbọn ati ẹgbẹrun lọna aadoje lekan(N131,000) ni wọn gba lọwọ wọn.

Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bolaji Salami tun sọ tẹlẹ pe Friday ti kọkọ ji alupupu(ọkada) kan gbe tẹlẹ lago ọlọpaa to ti n ṣiṣẹ.

Kọmiṣọnna ọlọpaa ni ẹjọ alupupu ti Friday ji lo n jẹ lọwọ nigba ti wọn gab mu pe o gbimọ pọ pẹlu sọja lati ja awọn eeyan lole pẹlu ọbẹ lọwọ.

''Lara awọn eeyan ti ja lole lo dawọn mọ nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa ṣe afihan wọn,'' Ọgbẹni Salami ṣalaye.

Ọga ọlọpaa naa ni awọn afurasi ọhun yoo foju ba ileẹjọ ni kete ti iṣẹ iwadii ba ti pari lori wọn.

Ẹwẹ, Victor to jẹ sọja ninu awọn afurasi naa ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn kan oun.