You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
School resumption: Ilé aṣojú-ṣòfin l'Abuja dábàá kí ìjọba sún ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ síwájú pẹ̀lú oṣù mẹ́ta torí covid-19
Ile aṣoju-ṣofin l'Abuja ti sọ pe ki ijọba apapọ sun ọjọ iwọle awọn akẹkọọ pada kuro lọjọ Aje ọjọ kejilelogun, oṣu kinni, ọdun 2021 yii.
Ile da aba pe ki ijọba sun iwọle awọn akẹkọọ siwaju pẹlu oṣu mẹta siwaju sii nitori bi arun coronavirus ti n pọ si lojoojumọ.
Alaga ile lori eto ẹkọ, Ọjọgbọn Julius Ihonvbere lo ṣi aṣọ loju eegun ọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lorukọ igbimọ rẹ.
- Àbámọ̀ ni yóò gbẹ̀yin ẹgbẹ́ ''Association of Stingy Men'' tí kò fẹ́ náwó f'óbìnrin- Akeugbagold
- Gomina Sanwo-Olu sún ọjọ "ṣiṣẹ lati ile" síwájú fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlà lọ́sẹ̀ tó kọjá tó fi mọ́ bí Covid-19 ṣe gbẹ̀mí èèyàn 23 lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Èèyàn 1,598 míì tún ti lùgbàdì covid-19 ní Nàijíríà, 1,420 ló ti kú báyìí
- Ẹ wo ọba kan nílẹ̀ Yorùbá, tí kò ṣe ètùtù tàbí náwó ànájù, kó tó jọba
Ọjọgbọn Ihonvbere sọ pe ijọba apapọ ko fi ọrọ iwọle awọn akẹkọọ to ile aṣofin leti ko to kede ọjọ ti wọn maa wọle pada.
Alaga igbimọ ile aṣoju-ṣofin sọ pe eeyan bi ẹẹdẹgbẹta lo n ni arun coronavirus lojumọ nigba tawọn ileewe wa ni titi pa.
Ṣugbọn Ọjọgbọn Ihonvbere ṣalaye pe o kere tan eeyan to le lẹgbẹrun kan lo n larun naa lojoojumọ bayii ti ijọba paṣẹ pe kawọn akẹkọọ pada sile iwe lọjọ kejidinlogun oṣu kinni yii.
''Kilode ti ijọba ṣe fẹ ṣe ileewe pada nigba ti ko tii si eto to mọyan lori lati rii pe ko ni ṣi ewu fawọn akẹkọọ lori ọrọ coronavirus ti wọn ba wọle pada bayii?'' Ọjọgbọn Ihonvbere lo beere bẹẹ.
Ihonvbere sọ pe ibeere to yẹ ki a bi ara wa ni pe ''ṣe a ti gbaradi fun wiwọle pada awọn akẹkọọ?''
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Edo ti sun iwọle awọn akẹkọọ nipinlẹ naa si oṣu to n bọ nitori bi coronavirus ṣe n gbilẹ sii lojoojumọ ni ipinlẹ naa.