You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Chisom Chukwuneke jẹ ìrora jẹjẹrẹ inú ẹjẹ̀ lásìkò tó n ṣe ìdánwò WAEC - Bàbá Chisom
Iyalẹnu nla ni yoo jẹ fun ọpọ eeyan lati gbọ pe ọmọdebinrin ti wọn ba sẹ ajọyọ bo ṣe gba A1 meje ninu idanwo WAEC rẹ lọdun 2019, Chisom Chukwuneke, ti jade laye.
Oun lo gba ami ẹyẹ akẹkọọ to tayọ julọ ninu idanwo WAEC lọdun 2019.
Ṣugbọn, aisan jẹjẹrẹ inu ẹjẹ 'leukaemia' ti ṣeku pa lọmọ ọdun mẹtadinlogun.
Ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, ni Chisom dagbere faye.
Ṣaaju iku rẹ, oun ni akọbi awọn obi rẹ.
Inu ibanujẹ si ni baba, iya, ati aburo rẹ, to jẹ pe oun lo tun ṣe daadaa julọ ninu idanwo WAEC ọdun 2020 nileewe rẹ.
Bawo ni Chisom ṣe lo igbeaye rẹ?
Ninu ọrọ to ba BBC sọ, baba rẹ, Ọjọgbọn Felix Chukwuneke, ṣalaye nipa bi ọmọ rẹ ṣe ja fafa, to si nifẹ awọn ọmọ bi i tirẹ.
O ni o ti n ṣaisan ki idanwo to bẹrẹ. Koda, o gba abẹrẹ lọjọ ti yoo joko ṣe idanwo Further Maths.
Ọjọgbọn Chukwuneke sọ pe iṣẹ imọ erọ ayarabiaṣa ni Chisom fẹ ṣe to ba dagba, amọ o yi ero rẹ pada lati ṣe iṣẹ imọ iṣegun oyinbo, nitori bi eto ilera ṣe ri ni Naijiria, ati ilera ara rẹ.
Iroyin sọ pe irora ẹsẹ ni ọmọ naa kọkọ n pariwo fun awọn obi rẹ, amọ ayẹwo pada fihan pe aisan jẹjẹrẹ inu ẹjẹ lo ni.
Eyi to mu ki wọn o gbe e lọ sileewosan kan lorilẹ-ede South Africa.
Nibẹ lo si ti n gba itọju lati bi ọdun kan, ko to o jade laye.
Baba Chisom, ti oun fun'ra rẹ jẹ onimọ iṣegun oyinbo ninu iṣẹ abẹ eyin ṣiṣe, to si tun jẹ olukọ ni Fasiti Naijiria, Nsukka, sọ pe asiko kan to sabi pe o ti n gbadun.
Amọ, jẹjẹrẹ naa pada pẹlu agbara ju ti tẹlẹ lọ.
O si ṣapejuwe ọmọ rẹ, ninu ọrọ idagbere to kọ si oju opo Facebook rẹ pe "goolu ni wọn fi kọ orukọ rẹ nibi ti o wa bayii".