Aisan Cancer pa ọkunrin kan lẹ̀yin ọjọ̀ díẹ̀ to jẹ milionu kan dọ́là

Arakunrin kan ti wọn pe orikọrẹ ni Donald Savastano ni ìbànújẹ́ ti pade ayọ̀ rẹ̀, nigba ti a gbọ pe o gbẹ́mìí mì lẹ́yìn ọjọ mẹ̀tadinlogun gééré to jẹ miliọnu kan owo dọ́là ninu ìyíkoto.

Arakunrin ọun, ẹni ọdun mọkanlelaadọta ni a gbọ́ pe o ti n ni awọn ipenija ilera ki o to di àsìkò ti ayẹwo fi han pe o ni aisan jẹjẹrẹ.

Wayi, ki o to di pe o jẹwó ninu iyikoto, Savastano ni a gbọ pe o jẹ kápẹ́ńtà, ti kò si ni owo tó tó lati tọju ara rẹ̀.

Sugbọn iroyin ibanujẹ ni o jẹ pe igba akọkọ ti arakunrin ọun o fojú ba ile iwosan fun itoju ni esi ayẹwo sọ pe o ni arun jẹjẹrẹ.

Savastano ni a gbọ pe o ti siwaju asiko yii sọ fun ile ise iyikoto ọun pe owo ti oun jẹ ọun yoo yi ìgbé ayé oun pada patapata. O ni oun o ra ọkọ̀ àjàgbé kan, oun o si lọ fun isinmi.

O ni ìrọ̀lẹ́ ọjọ kan ti oun n lọ ile oun ni oun ri ipolowo iyikoto ọun ti oun si gbiyanju rẹ̀ wò, ko to wa di pe oun jẹ obitibiti owó. O fi kúun pe oun ko ni ero kankan lori ìfẹ̀yìntì oun ki o to di ìgbà náà.

A gbọ pe Savastano ati ọrẹbirin rẹ ọjọ pipẹ Julie Wheeler ni wọn jọ n gbe titi o fi di ọjọ iku rẹ.