You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oúnjẹ alẹ́ lẹ́yìn aago mẹ́sàn án leè fa àrùn jẹjẹrẹ
To ba jẹ ọkan lara awọn to maa n pẹ, ko to jẹun alẹ, ajẹ pe o ni lati tun ero ara rẹ pa.
Idi ni pe iwadii kan fihan pe, awọn to maa n jẹun alẹ ki aago mẹsan an alẹ to o lu, tabi o kere tan, wakati meji ki wọn to o sun lalẹ, ni anfaani ida ogun, lati ma ni aisan jẹjẹrẹ ọyan ati jẹjẹrẹ ile itọ ọkunrin.
Eyi to pọ ju ti awọn to maa n jẹun alẹ ti wọn lẹyin aago mẹwaa tabi awọn to maa n sun loju ẹsẹ ti wọn ba jẹun tan.
Iwadii tuntun yii wa lati ọdọ ajọ Barcelona Institute for Global Health (ISGlobal) l'orileede Spain.
Wọn gbe abọ iwadii wọn naa jade ninu iwe apilẹkọ kan ti wọn fi sọri ibaṣepọ to wa laarin asiko ti awọn eniyan n jẹun ati jẹjẹrẹ ọyan pẹ̀lú asetọ̀ fun ọkunrin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Kini abọ iwadii naa?
Awọn onimọ ijinlẹ to se iwadii naa, ṣe agbeyẹwo idahun ti awọn eniyan okoo le lẹgbẹta o le ẹyọ kan (621) to ni jẹjẹrẹ ile itọ ọkunrin.
Pẹlu ti ẹgbẹrun le nigba ati marun-un (1,205) awọn to ni jẹrẹrẹ ọyan, to fi mọ ọrin le lẹgbẹrin o din mẹjọ (872) ọkunrin, ati ẹgbẹrun kan le ni ọọdunrun (1,205) obinrin ti ko ni jẹjẹrẹ.
Gbogbo wọn lo dahun awọn ibeere ti wọn fun wọn, lori igbe aye wọn, asiko ti wọn n jẹun, bi wọn ṣe n sun, ati awọn nkan mi i.
Igbagbọ awọn onimọ naa ni pe pipẹ jẹun lalẹ maa n mu ki ara ko wu, to si maa n mu iyatọ ba iye suga to wa ninu ẹjẹ.
Awọn nkan meji yii ni ibaṣepọ pẹlu jẹjẹrẹ.
Agbekalẹ agọ ara eniyan nilo ki eniyan tete jẹun, ki ounjẹ naa si da ki iru ẹni bẹ to sun.
Ṣugbọn, igbe aye ode oni, ko fi aaye silẹ fun ọpọlọpọ lati tete maa jẹun