You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Benin yóò gbẹ̀san lára Super Eagles nínú ìdíje AFCON tó ń lọ lọ́wọ́, torí bí Nàìjíríà kò ṣe jẹ́ ká lọ fún ìdíje 2026 World Cup - Olaitan Junior
Agbabọọlu ọmọbibi orilẹede Naijiria to n gbabọọlu fun orilẹede Benin, Junior Olaitan Ishola, ti sọ pe Benin yoo gbẹsan bi Super Eagles ko ṣe jẹ ki awọn pegede fun ife ẹyẹ agbaye 2026 World Cup.
Olaitan to n gbabọọlu lorilẹede Turkey sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC Yoruba wi pe bi Naijiria ṣe fagba han Benin ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ife ẹyẹ agbaye da bi apa ti ko le kuro lara awọn lailai.
''O dun wa gan an tori Benin ko tii kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ri.''
''Ọmọ agboole Onilu ni baba mi nilu Ajase nipinlẹ Kwara, inu mi si maa n dun si aṣa ati iṣe wọn nile baba mi''
Olaitan tun sọ pe nigba toun fẹ gbabọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Under-17 Naijiria, akọnimọọgba ikọ agbabọọlu naa sọ foun pe awọn to mọ bọọlu ju oun lọ wa kaakiri.
Agbabọọlu naa ni nnkan to ba oun ninu jẹ ni ọrọ ti akọnimọọgba ọhun sọ.
Olaitan ti ẹbi rẹ n gbe niluu Eko sọ pe ọmọ ilu Ajase nipinlẹ Kwara ni baba oun.
''Ọmọ agboole Onilu ni baba mi, inu mi si maa n dun si aṣa ati iṣe wọn nile baba mi,'' Olaitan lo sọ bẹẹ.