You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo bí ètò ìsìnkú Allwell Ademola yóò ṣe lọ
Lẹyin iku gbajugbaja oṣerebinrin tiata nni, Ọmọbabinrin Allwell Ademola, to waye lọjọ kẹta lẹyin ọdun Keresimesi to kọja, atẹjade to ṣalaye ilana isinku rẹ ti jade.
Ninu ikede naa ti Muyiwa Ademola, gbajumọ onitiata, fi soju opo ayelujara rẹ ni wọn ti kede pe eto isinku Allwell yoo bẹrẹ niluu Eko l'Ọjọbọ, ọjọ kẹjọ, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii.
Atẹjade isinku naa kede pe isin orin onigbagbọ yoo waye l'Ọjọbọ naa lati aago mẹrin irọlẹ titi di aago mẹfa.
Lẹyin eyi ni aṣalẹ titan abẹla yoo waye.
Gẹgẹ bi ikede naa ṣe wi, aago mẹfa irọlẹ ni titan abẹla yoo ti bẹrẹ, wọn yoo si ṣe e fun wakati kan.
Wọn fi kun un pe lati inu ọgba tẹlifiṣan ilu Eko (LTV) ni titan abẹla yoo ti bẹrẹ, wọn yoo rin de ikorita Oregun, wọn yoo si pari rẹ pada si LTV.
Lẹyin eyi ni alẹ awọn oṣere yoo bẹrẹ, wọn yoo si pari eyi si aago mọkanla alẹ.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹsan-an oṣu Kin-in-ni 2026 ni wọn yóò sin Allwell
Ọjọ yii ni won yoo sin Ọmọbabinrin Allwell Ademola.
Itẹ oku Atan, to wa ni Yaba niluu Eko ni wọn yoo sin oṣere tiata ọmọ ilẹ Ẹgba naa si, aago mẹwaa aarọ ni isinku yoo si waye.
Lẹyin isinku, atẹjade naa sọ pe ki kaluku gba ile wọn lọ ni.
Ninu ikede naa ni wọn ti dupẹ lọwọ gbogbo awọn to duro ṣinṣin ti awọn eeyan Allwell lẹyin ipapoda rẹ, fun ibanikẹdun ati ifẹ wọn.
Ni afikun, Rotimi Salami to jẹ ko-ri-ko-sun fun Allwell, kede pe aṣọ (T-shirt) ti wọn ya Allwell si pẹlu orukọ rẹ, yoo wa fun awọn olubanikẹdun lati wọ l'Ọjọbọ naa.
O ni eto ti wa fun eyi lati fun awọn eeyan ni aṣọ naa nibudo eto naa.
To ba di ọjọ Ẹti ti isinku yoo waye, o ni awọn eeyan le wọ ṣẹẹti funfun le ori aṣọ ti a mọ si Jeans.
Aṣọ funfun ni wọn ni ki wọn wọ wa.
Tẹ o ba gbagbe, ọkan Allwell Ademola ni wọn lo deede daṣẹ silẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2025, to si ṣe bẹẹ dagbere faye lẹni ọdun mọkandinlaadọta (49).
Rotimi Salami sọ ohun tí òun àti Olóògbé Allwell Ademola ń ṣe tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí kò ṣeé ṣe lọ́dún yìí
Iku ni ooya to n ya ọrẹ meji, to n ya ọkọ lẹyin iyawo, oun lo n gba ọmọ lọwọ obi ẹ, to n sọ ile alayọ di kikan lojiji lai si atunṣe.
Bẹẹ gẹlẹ lo ri lara gbajumọ oṣere tiata nni, Rotimi Salami, ẹni to jẹ ọrẹminu Oloogbe Allwell Ademola, oṣerebinrin to ku lọjọ Abamẹta to kọja.
Bi gbogbo onitiata ṣe n daro Allwell to ku lojiji, Rotimi ko tete sọrọ, awọn eeyan si n sọ pe o yẹ ki wọn ṣabẹwo si i.
Amọ nigba ti Rotimi Salami yoo sọrọ lọjọ kẹta iku Allwell, o ni oun sunkun asun-un-dakẹ fun wakati mejilelaadọrin, sibẹ, ọrẹ oun atata ko pada, o ti lọ si ajule ọrun.
O ni kawọn eeyan to n pe oun, fi atẹjiṣẹ ranṣẹ, ma ṣe binu pe oun ko tete dahun, ara oun ni ko le debi a n dahun nigba yẹn.
Nigba ti ọdun tuntun wa ku ọla, Rotimi tun ranti Allwell to maa n pe ni Sugar boo tabi Ẹniọbankẹ, nigba naa lo si kọ ọrọ si oju opo Instagram rẹ pe:
"Fun ọdun marun-un ni tẹle-n-tẹle, a jọ n wọnu ọdun tuntun labẹ orule kan naa ni"
Bi Salami ṣe kọ ọrọ idaro yii lo ni awọn jọ maa n gbadura, awọn si maa n beere ohun ti awọn fẹ, nibi ti awọn mọlẹbi Salami ti i ṣe ẹbi oun wa.
"Ti ọdun yii yatọ nitori o ko si nibi.
"Ninu ọkan wa ati adura… ni ohùn rẹ ati didimọ, a n ki gbogbo eeyan ku ọdun tuntun.
"Mo ti ṣeleri pe mo maa ni alaafia, mo si maa mu un ṣe."
Bẹẹ ni oṣerekunrin tiata Yoruba naa fi ẹdun ọkan daro Allwell, ẹni ti awọn kan sọ pe oun ati Rotimi n fẹ ara wọn ni wọn ṣe jẹ korikosun.
Ọpọ igba ni awọn eeyan ti beere lọwọ Rotimi Salami, pe ṣe ifẹ ikọkọ wa laaarin oun ati Oloogbe Allwell ni.
Ṣugbọn esi ti Salami maa n fọ ni pe ahesọ ni ọrọ naa.
Bo tilẹ jẹ pe orukọ bii Sugar Boo, Babe ati bẹẹ bẹẹ lọ ni won maa n pe ara wọn.
Wọn duro iṣẹju kan fun Oloogbe Allwell Ademola, nibi ayẹyẹ ọjọọbi oṣere tiata, Arike Gold
Fidio kan lori ayelujara, ṣafihan ayẹyẹ ọjọọbi kan to waye laipẹ yii, eyi ti I ṣe ti Adeola Folorunso, ẹni to pe ogoji ọdun toun naa si jẹ oṣere tiata.
Folorunso Adeola yii naa ni awon eeyan mọ si Arike Gold lagbo tiata Yoruba.
Nibi ayẹyẹ naa ti awọn oṣere wa, ni wọn ti ni ki wọn duro iṣẹju kan ni iranti Allwell Ademola, ẹni to ku lọjọ kẹta Keresi to kọja.
Ninu fidio naa ni awọn eeyan ti dorikodo laarin akoko iranti Oloogbe, ti awon mi-in si fa oju ro.
Wọn fi iṣẹju kan naa gbadura fun Allwell, ki ayẹyẹ too tun maa tẹsiwaju.
Ẹlomiran ti iku Allwell ṣi n ṣe ni kayeefi ni Biola Bayo toun naa jẹ gbajumọ oṣere.
Ninu ọrọ ti Biola kọ soju opo ayelujara rẹ laipẹ yii lo ti ni Allwell wa nile oun lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila 2025, ti i ṣe ọjọọbi oun.
O ni oun gbe e lọ wo sinima, oun tun gbe e pada sile oun, awọn si jọ ṣadehun lati jọ lọ sibi kan lẹyin eyi, ti won wa kede iku Allwell lẹyin wakati mẹrinlelogun.
''Allwell, ṣe o ti tan niyẹn?
Bẹẹ ni Biola Bayo beere ọrọ lai si esi fun un.
Ẹ o ranti pe ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2025 ni Allwell Ademole jade laye.
Ọkàn rẹ ni wọn lo deede daṣẹ silẹ, to si ṣubu lulẹ. Wọn gbe e lọ sile iwosan, ṣugbọn ẹpa o boro mọ.