Àwọn agbébọn 30 ya wọ àgọ́ Ọlọ́pàá l'Ondo, dáná sun ọkọ̀, ọ́fíìsì àti dúkìá olówó iyebíye níbẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọrọ di ẹni ori yọ o di ile nigba tawọn agbebon ya wọ ilu Ipele nijọba ibilẹ Owo nibi ti wọn ṣekọlu si agọ Ọlọpaa to wa ni ilu naa lanaa aisun ọdun tuntun.

Inu pọpọ-sinsin ọdun ni awọn ara ilu naa wa bi ọpọ ṣe n mura lati lọ si ile ijọsin fun isin aisun ọdun tuntun, nigba tawọn janduku agbebọn ọhun ya wọ ilu.

A gbọ wi pe ni ṣe ni ibọn n dun lakọ-lakọ bawọn janduku naa ṣe ya wọ ilu Ipele, eyi to mu ki awọn eniyan maa sa asala fun ẹmi wọ.

Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé?

Ọkan lara awọn olugbe ilu naa, Kehinde Olutimehin, salaye fun BBC Yoruba pe ẹmu ti oun ati awọn ọrẹ rẹ fẹ mu lati fi se aisun ọdun ni oun fẹ lọ ra ki oun to gbọ iro ibọn.

Olutimehin sọ pe banga ni oun kọkọ ro pe o n dun sugbọn laarin isẹju aaya, didun naa lagbara sii.

O ni nigba naa ni loun wa ri wi pe ibọn lo n dun lakọ-lakọ.

Osojumikoro naa sọ pe, gbogbo awọn to wa layika agọ Ọlọpaa sa asala fun ẹmi wọn

O salaye pe awọn agbebon naa da ina ibọn bole gidigidi ki wọn to sọ ina si agọ Ọlọpaa naa

Ọkan lara osojumikoro naa sọ pe, awọn Ọlọpaa obìnrin meji lo wa lẹnu isẹ lasiko ti awọn Agbebon naa n sakọlu wọn.

O sọ di mimọ pe, awọn obinrin meji naa ti bọ aṣọ wọn lasiko ti awọn ara ilu ri wọn, ti wọn si doola ẹmi wọn lati ma farakasa ibọn ninu akọlu naa.

Kí ni Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí?

Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti benu ate lu ikọlu awọn agbebọn si ẹka ileeṣẹ wọn to wa ni Ipele nijọba ibilẹ Owo nipinlẹ Ondo.

Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ naa, Abayomi Jimoh, sọ ninu atejade to fi sọwọ si awọn akọroyin pe awọn agbebon ti ko din ni ọgbọn ni wọn ṣekọlu si ileeṣẹ ọlọpaa naa.

O ni niṣe ni wọn da ibọn bolẹ ki wọn to lo ado oloro idungbamu (Dynamite) lati sọsẹ to lagbara.

Alukoro ọlọpaa salaye pe iṣẹlẹ yii waye ni deedee ago mẹwa ku isẹju mokandinlogun ni asale aisun ọdun tuntun.

O sọ di mimọ pe awọn to ṣekọlu yii sọ ina si ago Ọlọpaa to wa ni Ipele ti ọpọlọpọ ọkọ ati awọn ohun miran si jona di eeru.

Jimoh salaye pe iro to jina si ootọ ni wipe awọn agbebon naa ṣekọlu si ile ijọsin.

O tun fidi rẹ mulẹ pe ko si ẹmi to sọnu ninu iṣẹlẹ naa.

Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa naa salaye pe kete ti awọn gbọ iroyin ikọlu naa, ni agbarijọpọ awọn esọ alaabo to fi mọ ileeṣẹ Ọlọpaa, awọn ologun, esọ abo ara ẹni laabo ilu ati awọn ajọ miran ko awọn ikọ wọn lọ si oriko naa.

Amọ, o ni awọn agbebon naa ti sọsẹ tan ki wọn to de agọ olopaa naa.

Ogbeni Jimoh sọ pe Kọmisọna Ọlọpaa nipinlẹ Ondo Adebowale Lawal ti koro oju si ikọlu naa, o si ṣapejuwe iṣẹlẹ ọhun gẹgẹ bi eyi ti yoo fa ibẹru fawọn ara ilu.

Komiṣọna naa wa rọ gbogbo ara ilu paapa julọ awọn olugbe ilu Ipele ati agbegbe rẹ lati fi ọkan balẹ pẹlu idaniloju pe awọn agbofinro wa loju isẹ lati daabo bo gbogbo awọn olugbe agbegbe naa.