Aminu Yar'Adua: Ilé ẹjọ́ ju ọmọ Umar Musa Yar'Adua sí ẹ̀wọ̀n nítorí ẹ̀sùn ìpànìyàn

Ile ẹjọ Majisireeti kan ni ipinlẹ Yola, ti dajọ ẹwọn fun ọmọkunrin aarẹ Naijria nigba kan, Oloogbe Umar Musa Yar'Adua.

Ile iṣẹ iroyin Naijiria, NAN, jabọ iroyin pe ile ẹjọ ju ọkunrin naa, ẹni ọdun mẹrindinlogoji si ẹwọn nitori ẹsun pe o fi ọkọ pa eeyan mẹrun ninu ijamba kan nilu Yola.

Aminu Yar'Adua to jẹ akẹkọọ ni fasiti American University of Nigeria (AUN) Yola, ni ile ẹjọ fi ẹsun kan pe o wa ọkọ ni iwakuwa lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, eyi to yọri si iku awọn eniyan naa.

Ṣugbọn, Yar'Adua sọ pe oun ko jẹbi ẹsun naa, pe irọ ni.

Gẹgẹ bi iwe ipẹjọ ti agbofinro to n rojọ tako o nile ẹjọ, Zakka Musa ṣe sọ, Aminu Yar'Adua fi ọkọ kọlu eeyan mẹfa nigba to n wa ọkọ ayọkẹlẹ ni iwakuwa ni titi marosẹ ilu Yola.

O ni mẹrin lara awọn eniyan naa ku, ti meji yooku si fi ara pa.

Awọn eeyan naa la gbọ pe wọn wá lati abule Sabon Pegi, nijọba ibilẹ Gusu Yola.

Awọn to ku nibi ijamba naa ni Aisha Umar (ọgbọn ọdun), Aisha Mamadu (ọdun mejilelọgbọn), Suleiman Abubakar (ọmọ ọdun meji), ati Jummai Abubakar (ọgbọn ọdun).

Awọn to farapa ni Rejoice Annu (ọgbọn ọdun) ati Hajara Aliyu (ọdun mẹtadinlọgbọn).

Agbofinro Musa sọ pe awọn ẹbi oloogbe Aisha Umar, Jummai Abubakar ati Suleiman Abubakar n beere fun miliọnu mẹẹdogun Naira gẹgẹ owo itunu.

Onidajọ to n gbọ ẹjọ naa, Jummai Ibrahim ti sun igbẹjọ si ọjọ kọkandinlogun, osu Kẹjọ, ọdun 2021.

To si paṣẹ pe ki wọn o fi Aminu Yar'Adua si ẹwọn di ọjọ naa.