You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sani Abacha: Olórí ológun tí ìjọba rẹ̀ ga ju ilé ẹjọ́ lọ
Ọjọ nla ni ọjọ kẹjọ osu kẹfa ọdun 1998, nigba ti iroyin gba ilẹ kan pe, olori ijọba ologun ni Naijiria, ọgagun Sani Abacha ti silẹ bora
Iku ojiji to pa olori wa nigba naa, eyi to pe ọdun mejilelogun bayii, si lo n ṣe ọpọ eeyan ni haa-hii.
Ti a ba si ni ka kọ itan orilẹ-ede Naijiria, abala diẹ kọ ni oloogbe ọgagun Sani Abacha yoo ko nitori ipa manigbagbe to ko ninu isejọba Naijiria.
Idi ree ti BBC Yoruba fi ṣe akojọpọ igbe aye akọni ologun naa ati ọpọ iṣẹlẹ manigbagbe to gbe ile aye ṣe, lati la awọn ọdọ lọyẹ.
Igbe aye ati ohun manigbagbe ti Sani Abacha ṣe:
Ogunjọ oṣu kẹsan-an ọdun 1943 ni Sani Abacha dele aye nipinlẹ Borno, to si jẹ ẹya Kanuri amọ ilu Kano lo ti dagba, to si lọ sile ẹkọ nibẹ.
Ọdun 1963 ni wọn gba Sani sagbo iṣẹ ologun lẹyin to kawe nípa iṣẹ ologun nilu Kaduna lọdun 1969 ati nilẹ Gẹẹsi, to si ja fitafita ninu ogun abẹle Naijiria.
A kaa pe ọpọ iṣẹlẹ iditẹ gbajọba to waye ni Naijiria lo n lọwọ Abacha ninu nigba to si wa ni ipo 'second lieutenant' lasan, ibẹrẹ pẹpẹ si lo ti bawọn kopa ninu iditẹ gbajọba to waye losu keje ọdun 1966, to fi mọ eyi to waye lọdun 1983, to gbe ọgagun Ibrahim Babangida sori aga akoso.
Ọdun 1985 ti ọgagun Babangida si gba oye aarẹ ati Kọmanda awọn ologun ni Naijiria, naa ni Abacha gba oye olori Ileesẹ ọmọ-ogun ori ilẹ, to si tun di Minisita feto aabo lọdun 1990.
Lẹyin ti Babangida da ibo ọjọ Kejila osu kẹfa ọdun 1993 nu, ti gbogbo agbaye gba pe oloogbe Moshood Abiola lo jawe olubori ninu rẹ, ni rogbodiyan gbode, eyi to mu ki Babangida yẹba lori aleefa, ti wọn si fi Ernest Sonekan jẹ aarẹ fidihẹ ni Naijiria.
Amọ ọjọ Kẹtadinlogun oṣu kọkanla ọdun 1993 ni Abacha yẹ aga mọ Sonekan nidi, toun gangan si di aarẹ ologun ni Naijiria.
Isẹlẹ manigbagbe ti Abacha ṣe lori oye:
- Oṣu kẹsan-an ọdun 1994 ni Abacha kede pe ijọba oun ga ju aṣẹ ile ẹjọ lọ
- Abacha fragile ofin ologun 691 tọdun 1993, to si gbe ofin ologun miran kalẹ to fun ni agbara to ga julọ bii apaṣẹ waa, to si le ti ẹnikẹni mọle fun oṣu mẹta laisi gbe lọ sile ẹjọ
- Abacha sọ MKO Abiola si ẹwọn fun ẹsun iditẹ gbajọba tori pe Abiola pe ara rẹ ni aarẹ Naijiria, to si fiya jẹ ẹ titi ti Abiola fi ku
- O tun sọ Oloye Olusegun Obasanjo, Shehu Musa Yar'adua, Oladipupo Diya ati awọn eekan ilu miran si ẹwọn lori ẹsun igbidanwo iditẹ lati gbajọba.
- Abacha, lati ipasẹ Al Mustafa fi ọwọ lile dari Naijiria, Isẹlẹ Ado oloro yinyin gba ilu kan, ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ ajafẹtọ ilu ati ẹgbẹ to n ja fun ifẹsẹmulẹ ijọba alagbada NADECO, di ero ẹwọn.
- Lọdun 1997, Abacha ṣe afikun owo ti Naijiria n fi pamọ silẹ okeere lati $494m to wa lọdun 1993 si $9.6bn, ti adinku si ba gbese ti Naijiria jẹ lati $36bn si $27bn
- Iwa ajẹbanu gba ilẹ kan laye isejọba Abacha, ti oun funra rẹ si ko ọpọlọpọ owo Naijiria lọ fi pamọ fúnra rẹ ni oke okun, tawọn aya, ọmọ, ọrẹ ati alabasisẹ pọ rẹ naa si n ko owo ilu pẹlu, ninu eyi ti ijọba apapọ rí diẹ gba pada ninu owo naa to wa loke okun
- Abacha sọ ẹkun to wa ni Naijiria di mẹfa, to si tun da ipinlẹ tuntun miran silẹ
- Ijọba Sani Abacha lo tii buru julọ ninu iwa títẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ, to si pasẹ ki wọn yẹgi fun Ken Saro Wiwa atawọn Ogoni marun-un miran, to si tun ṣe idajọ Wole Soyinka lai si nile
- Abacha ko ipa manigbagbe si ogun to waye ni Liberia, to si ko awọn ọmọ ogun apẹtu-saawọ ransẹ
- Abacha ṣe agbekalẹ eto ipadabọ si eto oselu alagbada, ti oun naa si díje lati gbegba ibo aarẹ alagbada
- Amọ ọjọ kẹjọ osu kẹfa ọdun 1998 ni iku pa Sani Abacha nile ìjọba Aso Rock, ti wọn si lọ sin sile rẹ nilu Kano.