Ọkùnrin kan ṣe ìgbéyàwó fún obìnrin mẹ́rin lọ́jọ́ kan náà

Ọkunrin oniṣowo kan ti di gbajumọ lori ayelujara lẹyin to ṣe igbeyawo pẹlu obinrin mẹrin lọjọ kan naa.

Oniṣowo ọhun ti orukẹ rẹ n jẹ Mesmine Abeeole ṣe igbeyawo pẹlu awọn obinrin naa lagbegbe Libreville, lorilẹ-ede Gabon.

Iroyin kede orukọ awọn aya ọkunrin ọhun bii Madeleine Nguema, Prisca Nguema, Nicole Mboungou ati Carene Sylvana Aboghet.

Ọpọ awọn eeyan kaakiri agbaye lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori igbeyawo naa lẹyin ti awọran wọn jade lori ayelujara.

Diẹ lara awọn aworan igbeyawo naa ree: