Lagos Yoruba Nation rally: Ìjọba Eko jáwọ́ nínú ẹ̀sùn ìpànìyàn tó fi kan Ọba Ogboni

Ijọba ipinlẹ Eko ti jawọ kuro ninu ẹjọ ẹsun ipaniyan to fi kan ẹnikan lara awọn oluwọde Yoruba Nation, Tajudeen Bakare, to jẹ Olori ẹgbẹ Ogboni.

Ọjọ kẹta, oṣu Keje, ni awọn agbofinro mu Ọgbẹni Bakare pẹlu awọn oluwọde bi mẹtadinlaadọta lasiko ti wọn n ṣe iwọde ni Ojota, nipinlẹ Eko.

Lọjọ gan-an ni ibọn pa ọdọmọbinrin kan, Jumoke Oyeleke,nitosi ibi ti iwọde naa ti waye, ti ileeṣẹ ọlọpaa si sọ lasiko naa pe ibọn awọn kọ lo pa ọmọbinrin naa.

Lẹyin ọjọ diẹ ti Jumoke ku, ni ijọba ipinlẹ Eko ati ileeṣẹ ọlọpaa kede pe ẹnikan lara awọn oluwọde ti ọwọ tẹ (Ọgbẹni Bakare), ni iwadii fihan pe o pa ọmọbinrin naa.

Eyi to mu ko ṣi wa ni ahamọ awọn ọlọpaa botilẹ jẹ pe wọn ti gba beeli awọn ti wọn jọ ko wọn pọ nibi iwọde.

Ṣugbọn ni bayii, iroyin sọ pe wọn ti tu Ọgbẹni Bakare silẹ ni ahamọ agbofinro.

Ninu atẹjade to fi sita, eyi to tẹ BBC Yoruba lọwọ, agbẹnusọ fun ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, to jẹ ẹgbẹ to n ṣagbatẹru awọn iwọde Yoruba Nation, Maxwell Adeleye sọ pe wọn ti tu Ọba Ogboni silẹ.

O ni ijọba ipinlẹ Eko ti sọ pe oun jawọ lori ẹsun ipaniyan ti oun fi kan Ọgbẹni Tajudeen Bakare, Ọba Ogboni.

Bakan naa lo sọ pe wọn ti fi silẹ ko kuro ni ahamọ.