You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
History of Osun-Osogbo grove: Mọ̀ síi nípa ìtàn ojúbọ̀ Osun-Osogbo tó ti wà láti bi ẹẹdẹgbẹrin ọdún
Gbajugbaja ni ojubọ oriṣa Ọṣun nilẹ Yoruba, ati kaakiri agbaye fun awọn to jẹ olufọkansin fun oriṣa naa.
Ilu Oṣogbo nipinlẹ Ọṣun ni igbo Ọṣun-Oṣogbo naa wa, ni agbegbe Eti Oso Ọṣun.
- Yéèpà, òfin ìtakété síra ẹni forí ṣánpọ́n lásìkò ọdún Osun Osogbo
- Wọ́n ti ní kí Jolaosho "TBlak" wá káwọ́ pọ̀nyìn r'ojọ́ ìdí tó fi ya "Blue Film" nínú igbó Osun Osogbo
- Àwòrán àwòdamiẹnu rèé lásìkò ọdún Ọ̀ṣun Osogbo
- Ẹsẹ̀ kò gbèrò ní ọdún Ọ̀ṣun Òṣogbo
- Ọ̀ṣun Òṣogbo 2019 bẹ̀rẹ̀, àwọn iléeṣẹ́ àdáni ń bèèrè fún ẹ̀rọ ìgbàlódé láti sàfihàn àjọ̀dún
Ibẹrẹ Igbo/ojubọ Osun
Awọn onimọ nipa ẹsin abalaye ni Naijiria sọ pe o ti le ni nkan bi ẹẹdẹgbẹrin ọdun ti awọn alaalẹ to tẹ ilu Osogbo do, bẹrẹ sii ṣe ọdun Osun Osogbo.
Ọdẹ nla kan, Olutimẹhin, lo jẹ adari awọn eeyan kan to n wa ọna abayọ si ìyàn to mu nibi ti wọn tẹdo si tẹlẹ.
Erongba wọn ni lati kọ ile ti wọn o maa gbe si eti odo Osun, ṣugbọn bi wọn ṣe bẹrẹ si ni ge awọn igi to wa nibẹ, itan sọ pe oriṣa odo naa, Osun, pariwo jade si wọn, o si le wọn kuro nibẹ.
Lẹyin naa lo sọ fun ẹni to dari awọn eeyan naa, Olutimehin, pe ko ko awọn eeyan rẹ lọ si ibi pataki kan (to di ilu Osogbo).
Osun ṣeleri lati daabo bo wọn, ti yoo si fun wọn ni ọrọ pupọ. Kikii pe ki wọn ma a fun un ni ẹbọ lọdọọdun. Awọn eeyan naa gba lati maa ṣe bẹẹ. Ẹbọ ti wọn ma n fun un, lodi ọdun Osun Osogbo to n waye lọdọọdun bayii.
Lati igba naa si ni ibẹ ti di igbo mimọ nibi ti awọn olujọsin ti n korajọ lati sin jọsin fun.
Oun si ni igbo oriṣa to tobi julọ titi di ode oni ni ilẹ Yoruba.
- Kí ni apẹ̀rẹ̀ ikòlẹ̀sí ti Eko fi yàtọ̀ sí ti Ekiti tí ọ́ọ́físà mú wa mọ́lẹ̀?
- Òṣèré méjì yìí ń fi ẹ̀wọ̀n runmú tóríi fíìmù "Ife" táwọn obìnrin ń bá ara wọn lòpọ̀
- Ẹ wá wo ìgbà tí Jésù yóò dé - Pásítọ̀ Chris Oyakhilome
- Ilé ìtajà kan ni àwọn afurasí ọmọ Yahoo ti n bọ̀, kí ọlapàá SARS tó l'w wọn sí ẹnu ikú l'Osogbo
- Ẹ wó bí akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn ṣe rí òkú ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú kílásìí...
Ayẹyẹ ọdun Ọṣun-Oṣogbo
Lati mu ẹjẹ ti awọn to tẹ ilu Oṣogbo do, ṣe fun oriṣa Ọṣun ṣẹ, wọn bẹrẹ si ni ṣe ọdun irubọ fun un ni ọdọọdun.
Ọsẹ meji gbako ni ayẹyẹ ọdun Osun-Osogbo fi ma n waye.
Bi eto ọdun Ọṣun-Oṣogbo ṣe ma n lọ
Iwọpopo
Wọn o kọkọ bẹrẹ pẹlu ṣiṣe iyasimimọ ilu, ati ọna to lọ lati aafin Ataoja si igbo Ọṣun, ti wọn n pe ni Iwọpopo. Iya Ọṣun ati baba Ọṣun (Aworo) lo ma n ṣe eto yii.
Atupa olojumẹrindinlogun
Lẹyin ọjọ mẹta ni wọn o tan atupa kan to ti wa fun ẹẹdẹgbẹta ọdun, ti wọn n pe ni atupa olojumẹrindinlogun.
Ina atupa yii yoo wa ni titan laarin aago meje irọlẹ si meje owurọ, ti Ataoja ati awsn iyawo tẹ, pẹlu babalawo yoo si jo yiika lẹẹmẹta loju gbogob ara ilu to ba peju si aafin.
Iboriade
Lẹyin eyi ni 'Iboriade', to jẹ asiko ti wọn o to ade gbogbo awọn ọba to ti jẹ nilu Osogbo, fun ìre lati ẹnu Ataoja ilu Oosgbo, Arugba Osun, Yeye Osun, ati awọn iya oloriṣa.
Arugba Osun, ni omidan ti ko ti ni ibalopọ ri, to ma n ru igba Osun ti wọn ko ẹbọ ti wọn fẹ ẹ gbe fun oriṣa Osun.
Ojuṣe Arugba ju gbigbe igba nikan lọ. O jẹ alarina laarin awọn eeyan ati Osun.
Lasiko to ba ru igba naa, wọn ma n fi orogbo meji si ni ẹnu, ko ma ba a le sọ awọn nkan to wa ni ọkan rẹ nipa wiwọ igbo Osun.
Ko tan sibẹ o, omidan naa ko gbọdọ kọsẹ tabi ṣubu, bibẹẹkọ, apẹẹrẹ buruku ni fun un, ati ilu Osogbo.
Itan sọ pe nkan buruku ni yoo ṣẹlẹ ni ilu ninu ọdun to ba tẹle.
Sussane Wenger to di Adunni Oloriṣa
Ni nkan bi ọdun 1950, itan sọ pe nkan dẹnu kọlẹ ninu igbo oriṣa Osun-Osọgbo, nitori pe awọn eeyan ko fi bẹ ẹ lọ si awọn ojubọ oriṣa mọ, awọn alawo naa fi ojuṣe wọn silẹ.
Ṣe oju to ba dilẹ ni rorẹ n sọ - bi nkan ṣe ri mu ki awọn eeyan kan bẹrẹ si ni mu ẹja ninu odo naa, wọn ṣe ọdẹ ẹran, koda wọn n ge igi, eyi to jẹ ewọ tẹlẹ.
Bayii ni nkan ṣe ri titi ti oyinbo alawọ funfun, ọmọ orilẹ-ede Austria, Sussane Wenger to pada di Adunni Olorisha, fi de si ilu Oṣogbo, to si fi opin si awọn iwa ibajẹ to n waye ni inu igbo naa.
Pẹlu iranlọwọ Ataoja ilu Oṣogbo, ati awọn ara ilu, Wenger bẹrẹ eto kan to fi sọri gbigbogun ti awsn to n lo igbo naa lọna aitọ, to si tun ṣe atunṣe ibi mimọ naa.
Lọdun 2005, ajọ UNESCO kede igbo Ọṣun-Oṣogbo gẹgẹ bi ibudo iṣẹmbaye ajogunba, ti pe ni World Heritage Site.