You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
PDP youth leader jailed: Bí Kato ṣe d'èrò ẹ̀wọ̀n torí ó bú Buhari, Boss Mustapha
Ile ẹjọ́ Majisireeti kan ni Yola, Ìpínlẹ̀ Adamawa tí dajọ pé wọn rán olórí àwọn ọdọ lẹgbẹ òṣèlú Peoples Democratic Party ni ijoba ibile Hong, tí orúkọ rẹ ń jẹ Ikamu Kanto lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan gbáko.
O ri ẹwọn he látàrí pé ó sọ̀rọ̀ àbùkù sì Ààrẹ Naijiria, Ogagun Muhammadu Buhari ati akọ̀wé ijoba àpapọ̀, Boss Mustapha.
Àwọn iwe iroyin sọ pé wọn fi olórí ọdọ náà sì ẹ̀wọ̀n lórí esun kan tí àwọn alatileyin akọ̀wé àgbà ijoba àpapọ̀ fi kan an lábẹ́ aburada ẹgbẹ́ to ń jẹ "Adamawa Concerned Citizens" èyí tí Husseini Gambo dárí.
- Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..
- Ẹ wó bí akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn ṣe rí òkú ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú kílásìí...
- Dáa padà! Àwa kìí ṣe ẹgbẹ́ kan náà pẹ̀lú APC tó dojú Nàìjíríà kodò -PDP sí Jega
- Wo àmí ẹ̀yẹ tí Abba Kyari tí gba gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtagìrì ọlọ́pàá kí wọ́n tó fi ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu kàn án
- Ta ni Tunji Disu ti wọ́n kéde láti rọ́pò Abba Kyari?
- Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ "baby" bóo ṣe jẹ́ kí ọkùnrin míì gbẹ́nu sí ìdí, ọyàn rẹ nílé Ẹlẹ́gbọ̀n-ọ́n àgbà BB Naija - Ọkọ Tega
Ní ọ̀sẹ̀ to koja, wọn pé Kato kò wá kawọ ponyin ro ẹjọ́ nípasẹ̀ ọ́fíìsì àjọ Otelemuye DSS nípasẹ̀ ọ́fíìsì Agbejoro àgbà.
Kato sọ pé nítorí ìbínú bí ikọ Boko Haram ṣe kọlu ìlú Dabna níbi tí èèyàn tó lè ní ogún ti padanu ẹ̀mí wọn lo mu ki òun bọ si oju òpó Facebook láti fun pe sì akowe àgbà àti Ààrẹ Buhari.
O ni ki wọn le tun tẹsiwaju lori pipese eto aabo to peye ni.
O tun ni lórí kikuna láti dá abo bo ẹ̀mí àwọn olùgbé ìlú náà tó jẹ́ ijoba ìbílẹ̀ tìrẹ to sì tún jẹ́ ibi tí akowe àgbà náà tí wá
Lẹyin tí adajọ Majisireeti náà, Dimas Elishama gbọ́ ẹjọ́ náà, ó ní Kato jẹbi ẹ̀sùn tí wọn fi kan an ó sì rán án lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdun kan pelu faani egberun meedogbon náírà fún pé ó lo àwọn ọ̀rọ̀ àbùkù àti alufansa.
- Ta ni Tunji Disu ti wọ́n kéde láti rọ́pò Abba Kyari?
- Wo àmí ẹ̀yẹ tí Abba Kyari tí gba gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtagìrì ọlọ́pàá kí wọ́n tó fi ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu kàn án
- Ẹ wó bí akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn ṣe rí òkú ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú kílásìí...
- Dáa padà! Àwa kìí ṣe ẹgbẹ́ kan náà pẹ̀lú APC tó dojú Nàìjíríà kodò -PDP sí Jega
- Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí gbajúmò ọlọ́pàá, Abba Kyari tí wọ́n kó pọ̀ mọ́ "rógà" pẹ̀lú Hushpuppi?
- Àwọn dókítà da iṣẹ́ sílẹ̀ káàkiri Naijiria, ilé ìwòsàn dá páròpáro!
Ilé ẹjọ́ ni àwọn tí gbó ẹ̀bẹ̀ rẹ pé kí àwọn fi ojú àánú wo ọrọ náà, wọn tún wo ìhùwàsí rẹ lásìkò ẹjọ́ náà ni wọn ba fi kún un pé kò ní lọ lai jìyà sugbọn yóò jìyà láti jẹ àpẹrẹ fún àwọn tó kú.