Abba Kyari, Tunji Disu: Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọ̀gá ọlọ́pàá tí wọ́n fi rọ́pò Abba Kyari

A bi Tunji Disu ni ọjọ kẹtala, oṣu kẹrin, ọdun 1966 ni ipinlẹ Eko ni guusu iwọ oorun Naijiria.

O ti figba kan ṣe igbakeji kọmiṣọnna ọlọpaa ri ni abuja, o tun ti jẹ adari ajọ iṣẹ akanṣe ninu agbofinro ni ipinlẹ Eko, iyẹn Lagos State Rapid Response Squad (RRS).

Disu kẹkọọ gboye ninu ede Oyinbo lati Fasiti ipinlẹ Eko LASU

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti kede ọgbẹni Tunji Disu gẹgẹ bii adari tuntun fun ẹka to n ri si ifimufinlẹ lori ọrọ awọn ọdaran, IRT.

A bi Tunji Disu ni ọjọ kẹtala oṣu kẹrin, ọdun 1966 ni ìpínlẹ̀ Eko, ni ẹkun Gúúsù iwọ-oorun Nàìjíríà

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti kede ọgbẹni Tunji Disu gẹgẹ bii adari tuntun fun ẹka to n ri si ifimufinlẹ lori ọrọ awọn ọdaran, IRT.

Ipo ti ileeṣẹ naa fi Disu si yii ni gbajugbaja ọlọpaa Abba Kyari wa tẹlẹ ki wọn to jawe lọ rọkun nille fun lẹyin ti ijọba ilẹ Amẹrika fẹsun kan pe o n ba afurasi onijibiti, Hushpuppi dowopọ.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ naa, Frank Mba buwọlu niluu Abuja, o ni ọga agba ileeṣẹ naa ni Naijiria, Usman Alkali Baba lo paṣẹ pe ki wọn fi Disu si ipo naa.

Kéére óò! Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá tí yan igbákejì Kọmiṣọnna ọlọ́pàá,Tunji Disu ní olórí ikọ̀ àmúsẹ̀yá àwọn Ọlọpaa

Mba sọ pe wọn yan Disu si ipo tuntun ọhun, ki iṣẹ ẹka naa le maa tẹsiwaju lai si idiwọ kankan.

Ki wọn to yan Disu si ipo tuntun yii, o ti ṣiṣẹ ni ẹka to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, RRS, nipinlẹ Eko.

Bakan naa ni o wa ni ipo igbakeji kọmiṣọnna ọlọpaa nillu Abuja.

Disu yii kan naa ti ṣiṣẹ ni ipinlẹ Rivers ri, iyẹn ni ẹka ti wọn ti n ṣe iwadii iwa ọdaran, CID, nibi to ti ṣe gudugudu meje ati yaya mẹfa.

Tunji Disu wa lara awọn ọlọpaa to lọ ṣoju Naijiria lati da alaafia pada siluu Dafur, iyẹn lorilẹ-ede Sudan.

O kawe gboye nipa ede Gẹẹsi ni fasiti ijọba ipinlẹ Eko, LASU.

Lẹyin naa lo kawe siuwaju ni fasiti Adekunle Ajasin, to wa niluu Akungba-Akoko, nipinlẹ Ondo.