Michael Salako and bike man death: Àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ mú arákùnrin ẹní ogójì ọdún tó fí ìbínú lu Abudu ọlọ́kadà pa ní Abeokuta

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun ti ṣe afihan arakunrin kan to fi ibinu lu ọlọkada kan pa nitori pe o kọ lati gbe jade.

Micheal Salako la gbọ pe ọwọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ọlọpaa ti tẹ lagbegbe Lafenwa ni Abeokuta tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi ti ṣe sọ afurasi yi ti mọ ọlokada naa tipẹ nitori adugbo kan naa ni wọn jijọ n gbe.

Abimbola sọ pe lẹyin tawọn gba ọrọ lẹnu rẹ, Micheal ni oun lọ beere lọwọ Abudu tii ṣe ọlọkada naa pe ki lo de to kọ lati gbe oun jade lana.

Nibi tawọn mejeeji ti n fa ọrọ naa ni ija ti bẹ silẹ ti Abudu si ṣubu lulẹ to si gba ibẹ di ero alakeji.

Alukoro ọlọpaa tẹsiwaju pe wọn ti gbe oku ọlọkada naa lọ si aaye igbe oku pamọ si ni mọṣuari lati le ṣayewọ lori ohun to ṣeku pa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ṣeleri lati ṣayẹwo ni kikun lori ohun to ṣokunfa iku Abudu ọlọkada naa.