You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Buhari Oloto: Gbajúmọ̀ ọba tó lo sàá lágbo fàájì ìlú Eko fún ogójì ọdún ó le
Agba akọrin, Ajinhinrere Ebenezer Obey-Fabiyi ti ṣapejuwe iku ọba alaye kan nilu Eko, to ku laipẹ yii, Alhaji Buhari Oloto, gẹgẹ bi adanu nla fun oun.
Ebenezer Obey sọ pe iyalẹnu ni iroyin iku rẹ jẹ fun oun, to si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi alatilẹhin oun timọtimọ fun ọpọlọpọ ọdun.
Ọjọbọ ni iroyin iku Ọba Oloto, to tun jẹ gbajumọ nilu Eko, jade sita.
Nigba aye rẹ, oun ni Ọba alaye ilẹ Iguru, Aguda, Surulere nipinlẹ Eko.
Oṣu Kẹsan-an, ọdun 2020 ni ọba naa pe ẹni ọgọrin ọdun.
Ninu oṣu naa paapaa ni wọn gbe ade le e lori gẹgẹ bi ọba.
- "Tinubu ò kú o, àlááfíà ló wà, àmọ́..."
- Wo ohun mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Rachel Oniga tó d'ágbére f'áyé
- Èyí ni àlàyé lórí ètò ìsìnkú Tope AjogbaJesu àti ọjọ́ tí wọn yóò sin ín
- Ohun tí ìyá tó bí mi lọ́mọ rò rèé tó fi ní kí n má yà sídìí iṣẹ́ orin kíkọ - Ebenezer Obey
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa "food poisoning" àti bí o ṣe lè dẹ́kun rẹ̀
- Ẹ̀yin ọmọ Nàíjíríà, mó rí ìlàkàkà yín, ẹ ṣe sùúrù nítórí ìyá yìí yóò dópìn - Ààrẹ Buhari
Ta ni Buhari Oloto to doloogbe yii?
Bakan naa ni iroyin sọ pe oun ni ọba akọkọ to jẹ, ni Aguda-Surulere.
Awọn olorin bi oloogbe Sikiru Ayinde Barrister, to si tun jẹ ọrẹ pẹlu rẹ, Wasiu Ayinde, Ebenezer Obey, ati bẹẹ bẹẹ lọ, naa maa n ki i ninu awọn orin wọn nigba aye rẹ.
Koda, Oloto jẹ ilumọọka lagbo faaji fun ọpọlọpọ ọdun.
Botilẹ jẹ pe a ko le sọ nkan to pa baba agba naa, iroyin sọ pe ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo, Lagos State University Teaching Hospital (LASUTH) lo ku si.
Obey, to wa ni orilẹ-ede United Kingdom lọwọlọwọ, sọ pe alẹ Ọjọbọ ni oun gbọ iroyin Ọba Oloto nilu London ti oun wa.
O ni: eyi to jẹ ibanujẹ nla fun oun, nitori pe oun padanu ẹnikan lara awọn ọrẹ oun timọtimọ, to tun jẹ ololufẹ oun fun ọpọlọpọ ọdun.
Obey ni "lati igba ti Oloto ti wa ni ọdọmọkunrin, ni oun ati ẹgbọn rẹ, Sogunro, ti ma n wa wo mi ti mo ba n patẹ orin ni Miliki Spot ni gbogbo ọjọ Aje ati Ọjọbọ ni nkan bi ọdun 1970.
Ebenezer ni: "Koda, lẹyin ti Sogunro ku, Buhari ṣi maa n wá ."
O ni oun yoo ṣafẹri oloogbe naa pupọ nitori pe eniyan daadaa ni.