Oniduromi: Taní Wolí rẹ̀? ẹ wò mí bí mo ṣe lọ ''minister'', tí Woli Joshua Iginla fí ọkọ̀ ńla ta mí lọ́rẹ - Adeyinka Alaseyori

Evangelist Yinka Alaṣeyori ti fi idunnu rẹ han lori bi Woli rẹ, Josua Iginla ṣe fi ọkọ bọgini ta a lọrẹ.

Alaṣeyori naa lo lọ kọrin ni ile ijọsin wọn to wa ni ilku Abuja ti wọn pe ni Champions International, lorilẹede Naijiria.

Alaṣẹyọri lasiko to n fi idunnu rẹ han bẹrẹ ibeere wi pe tani Woli rẹ, nibo ni ile ijọsin rẹ, to si gbadura fun woli rẹ naa.

''E wo ni ki a lọ minister, ki a gba honourarium to lamilaaka, ki wọn tun fi ọkọ bọgini, mọto ẹlẹṣẹ mẹrin ta wa lọọrẹ.?''

Bakan naa lo bẹrẹ si ni kọ orin lati fi idunnu rẹ han pe aanu ni oun ri gba.

Alaṣeyori ni igba akọkọ ni yii ti oun yoo ri Woli Joshua Iginla, ti oun si lọ si ile ijọsin rẹ.

O ni ko sọ wi pe ki oun polongo ore to ṣe fun oun, amọ lati fi idunnu oun han ni oun ṣe gbe si ori ẹr ayelujara wi pe aanu ni oun ri gba.

Ko pẹ ti olorin ẹmi ,Yinka Alaseyori di ilumọka lẹyin ti gbas gbos waye ni aarin rẹ ati olorin ẹmi, Tope Alabi to sọrọ orin rẹ, Oniduromi, to si ni pe ko tọ ki o pe Ọlọrun ni "Oniduro Mi".

Amọ awọn ọmọ Naijiria faraya, ti wọn si sọrọ kubakugbe si Tope Alabi wi pe ko tọ si lati tabuku.

Lẹyin naa ni Adeyinka Alaseyori kọkọ ṣebi ẹni ti ko fẹ mẹnu ba ọrọ yii rara lati igba to ti ṣẹlẹ, amọ ni ibi ti o ti n ṣe isin orin iyin lati ṣaami ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lo ti bẹ gbogbo awọn eeyan lori ọrọ yii.

Lo ba tun fi adura bọ ẹnu fun gbogbo awọn to n ṣe iṣẹ to jẹ ọna to tọ pe: "gbogbo ẹyin tẹ n ṣe iṣẹ ọna to tọ to n mu ounjẹ wa sori tabili yin, ẹ o maa lowo sii ni".