You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tope Alabi, ìyá mi ló jẹ́..., àmọ́ mo fẹ́ ... - Yinka Alaseyori
Iroyin to n jade lọwọlọwọ ni pe olorin ẹmi to ti di ilumọka bayii laarin ọjọ mẹta pere, Yinka Alaseyori ti sọrọ soke si bi ogbontarigi olorin Tope Alabi ṣe sọrọ ni gbangba pe ko tọ ki o pe Ọlọrun ni "Oniduro Mi". O ti fi ọrọ ranṣẹ si Tope Alabi ati gbogbo eeyan.
Adeyinka Alaseyori kọkọ ṣebi ẹni ti ko fẹ mẹnu ba ọrọ yii rara lati igba to ti ṣẹlẹ gẹgẹ bi ko ṣe ba ile iṣẹ́ iroyin kankan sọrọ lati ọjọ yii ti pada fọhun.
Nibi ti Yinka Alaseyori ti n ṣe isin orin iyin lati ṣaami ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ lo ti bẹ gbogbo awọn eeyan lori ọrọ yii.
Lo ba tun fi adura bọ ẹnu fun gbogbo awọn to n ṣe iṣẹ to jẹ ọna to tọ pe: "gbogbo ẹyin tẹ n ṣe iṣẹ ọna to tọ to n mu ounjẹ wa sori tabili yin, ẹ o maa lowo sii ni".
Alaṣeyori ni ti oun ba ti ṣe tan nibi eto orin iyin naa, ounjẹ loun n lọ jẹ gẹgẹ bo ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ to jẹ ọjọ kẹrin oṣu kẹfa gangan amọ to ni ko saye lati ṣe ayẹyẹ afi titi di oni ti oun fi ṣe eto orin iyin.
Ọ̀rọ̀ tí Alaseyori sọ nípa Tope Alabi
Lẹyin ọpọlọpọ wakati orin iyin ti akọroyin BBC Yoruba joko ti loju opo ayelujara Adeyinka Alaṣeyori funrarẹ, ti oun ati olorin ẹmi mii Dare Melody kọ lati fi ṣide eto naa, Alaseyori fẹ re si orin alujo tori o ni "mo fẹ ki ẹ jo amọ mo fẹ fi Ọlọrun bẹ yin..."
Alaseyori ni "mo kọkọ fẹ dupẹ lọwọ gbogbo eeyan kaakiri agbaye, loke okun ati nile nibi fun ifẹ yin. "Mummy Tope Alabi, iyaa mi ni".
O tẹsiwaju pe: "Iya ni Tope Alabi jẹ si mi, ọna kan tabi omiran si ni gbogbo wa ti jẹ anfani lara awọn orin rẹ... Ẹ jọwọ ẹ jẹ ki alafia jọba".
Alaseyori ti ijo ati ohun orin didun si ba nile tẹlẹ ti gbogbo ijo wa lara rẹ - lo ba ni kan si orin ati ijo si Ọlọrun ati fun awọn ololufẹ rẹ.
Ṣe Aladeyori tun orin Oniduro Mi kọ tabi o mẹnu kuro nibẹ?
Yinka Alaseyori ko mẹnu ba idi kankan ti ko fi yẹ ki o kọ orin naa gẹgẹ igun awọn eeyan kan ṣe n ja fun pe kii ṣe ohun gangan ni Ọlọrun fun ni orin naa lati kọ kalẹ.
Iroyin ti a kojọ ati ifọrọwanilẹnuwo BBC Yoruba pẹlu ni ti o gba imisi orin naa gangan, Evangelist Toluwalase Aladelegan fihan pe ọdun 2014 ni Tolu gba imisi orin naa to si tun kọ jade ni ile ito orin pọ.
Ẹwẹ, Alaṣeyori to jẹ́ olorin ẹmi to maa n kọ gbogbo orin yala tirẹ ni tabi ti ẹlomiran bi o ba ṣe ni idari kẹnu bọ awọn orin to wu awọn eeyan lori gan. Diẹ lara wọn niyii:
Iṣẹ nla lẹ ṣe laye mi
Ẹyin tẹ fun wa lowo tẹ́ẹ fun wa laṣọ, fun wa ni ipara, ẹ o maa lowo, lọla sii.
Ọlọrun ko da bi eniyan, eeniyan aronipin... Iwo ko lo da mi, iwọ kọ lo bi mi, o si n sọrọ bi Eledumare
Jesus na you big o, Ọga patapata...
Ẹ ṣee aye ọpẹ yọ, mo dupẹ aye ọpẹ pada yọ
N o la agbaye ja, n go si ri bi Ọba...
Oniduro Mi ẹ ṣeun o...