Jumoke Autopsy Report: Èsì àyẹ̀wò ní ìbọn ló pa Jumoke l'Ojota àmọ́ ọlọ́pàá ní àpá ọ̀bẹ wà lára òkú rẹ̀

Ayẹwo fihan pe Jumoke Oyeleke ti iroyin sọ pe ọta ibọn pa nibi iwọde fun idasilẹ Yoruba Nation ni Ojota l'Eko gbẹmi mi, lẹyin ti ẹjẹ di si ọkan rẹ eyi t'awọn oloyinbo n pe ni "hemopericardium."

Ayẹwo tun fihan pe ọta ibọn bá a ni aya eyi to ṣakoba fun ẹdẹforo rẹ.

Ile iwosan LASUTH lo gbe esi ayẹwo naa jade gẹgẹ Dokita S.S. Soyemi ṣe sọ.

Esi ayẹwo oku Jumoke tun fihan pe laago mọkanla aabọ aarọ ni o jẹ Ọlọrun nipe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa Eko sọ pe apa ọbẹ wa lara oku Jumoke eyi to fihan pe o ṣeéṣe ko jẹ pe awọn kan lo gun ùn lọbẹ pa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ibi ti awọn ti ri oku Jumoke jina si ibi ti iwọde ti n waye.

Wọn lẹyin ileepo MRS lọna Maryland lawọn ti ri oku Jumoke ti wọn si we oku naa laṣọ.

Koda wọn ni ẹjẹ ti gbẹ tan lara oku ọhun.

Awọn to wa nibi iwọde naa sọ pe Jumoke ṣagbako iku ojiji dero ọrùn lẹyin tawọn ọlọpaa ṣí aarin awọn olufẹhonuhan lati tu wọn ka lọjọ kẹta oṣu keje.

Wọn ni aṣita ibọn lo gbẹmi lẹnu Jumoke.

Amọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni awọn agbofinro to wa nibi iwọde naa ko tilẹ yinbọn rara .

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Muyiwa Adejobi ṣalaye pe oku Jumoke, ẹni ọdun mẹẹdogbọn fihan pe kii ṣe ọjọ iwọde ọhun lo gbẹmi mi.

Adejobi ni apa to wa lara rẹ ṣe afihan iru iku to pa a.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni esi ayẹwo ohun to pa Jumoke ti LASUTH gbe jade ko t'ọna.

O ni wọn kan fẹ fi esi naa da ibẹrubojo silẹ ati pe wọn fẹ gbin ibẹru sí ọkan awọn eeyan ipinlẹ Eko ni.

Ẹwẹ, aṣoju ẹbi Jumoke, Ọgbẹni Afolabi Wasiu sọ fawọn akọroyin pe wọn kò ri ọta ninu ara Jumoke.

Ọgbẹni Wasiu ni ayẹwo fihan pe ọta naa jade lara rẹ lẹyin to ba a tan.

O ni ileeṣẹ ko tii fún ẹbi Jumoke labọ iwadii wọn lori iku to pa a.