Oshogbo Heavy Rainfall: Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá àìmoye mílíọ̀nú naira ṣòfò nínú ìjàmbá omíyale

Okere tan, oku eeyan mẹta lawọn aradugbo ti ri lẹyin ijamba omiyale agbara ya ṣoobu to waye ni Ipinlẹ Osun lỌjọru.

Wakati mẹrin gbako ni ojo yi fi rọ tawọn adugbo kọọkan ni Osogbo ati Erin Osun si farakasa ojo arọrọda yi.

Ọpọ dukia lo ba iṣẹlẹ naa lọ eyi taa gbọ pe o bẹrẹ si ni rọ lati oru ọjọ Iṣẹgun ti ko si da titi di owurọ kutu Ọjọru.

Ni adugbo Oke Ijetu ati Oke Oniti, wọn ri oku eeyan meji ti awọn ile kọọkan naa si faragba omiyale yi.

Ṣoobu itaja ni Rasco, Obate, Atimowa, Testing Ground, Awosuru, Oke Ayepe ati ni Ita Olokan naa ko moribọ ninu ijamba yi.

Ara aradugbo Oke Ayepe kan to ba iwe iroyin Naijiria Punch sọrọ ṣalaye pe o ṣoju oun nigba ti wọn gbe oku arabinrin kan sọkalẹ lori igi to ha si.

O ni awọn musulumi to fẹ ki irun ayila lo ri oku naa loju agbara odo Okooko nibi to ha si aarin igi ọpẹ meji.

Gomina Oyetola ba araalu kẹdun

Adugbo Alie nijọba ibilẹ Olorunda ni Gomina Adegboyega Oyetola ti duro ba awọn aradugbo kẹdun lori iṣẹlẹ omiyale.

Lasiko to n kaakiri lati ri bi ojo ṣe ba nkan jẹ. o ni o ṣe pataki ki awọn araalu maa tẹle ilana itọju ayika ẹni paapa eyi to ni ṣe pẹlu oju agbara.

''Pẹlu nkan taa ri, o fi han pe oju agbara to di latari bi awọn eeyan ṣe n da panti soju agbara lo da wahala silẹ.Ni ọpọ ibi, niṣe lawọn eeyan gbegi dina oju agbara''