Deaths in July: Àwọn ìlúmọ̀ọ́ká Mẹ́wàá to kú nínú oṣù keje odun 2021

Háà o máa ṣe lo gba ẹnu ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà nínú oṣù keje ọdún 2021 bi ikú se mú àwọn gbajúgbajà kan kúrò ni Dúníyàn

Mẹ́wàá ninu àwọn ti ikú nawọ́ mú rèé:

1.Rachel Oniga:

Ọmọ bibi ipinlẹ Delta ro tun jẹ ilumọọka osere tiata Nollywood Rachael Oniga gba ekueu jẹ lọwọ ẹbọra ni ọgbọn ọjọ, oṣu keje, ọdun 2021.Ẹbí Rachael Oniga kéde ètò ìsìnkú òṣèré tó d'olóògbé

Ẹni to di Gbajugbaja ninu sinima, Owo Blowku ni deede aago mẹwaa ọjọ naa gẹgẹ bi awọn ẹbi rẹ ṣe fi lede.

Ọdun 1993,lo bẹrẹ ere tiata ti o si ri kopa ninu awọn oniruuru sinima.

2. Tope Ajogbajesu:

Tope Ajogbajesu, to jẹ ẹbi awọn Gbajugbaja olorin ẹmi naa ku ninu oṣu keje.

Jide Ajogbajesu kede pe ibanujẹ ọkan ni lati kede pe awọn padanu ẹni ti ọkan awọn fẹ Tope Ajogbajesu.

3. Bala Bantex:

Igbakeji Gomina ana ni Kaduna Barnaba Bala Bantex naa ku lẹni ọdun mẹrinlelọgọta lẹyin aisan ranpẹ.

4Buhari Oloto :

Gbajugbaja Ọba Alahaji Buhari Olotonaa ku ninu oṣu kwjw ni ile iwosan ikọni ti ilu Eko ro wa ni Ikeja. Ta a ni ọ̀rẹ́ tóòtọ́, Ọba Buhari Oloto tó kú tó mú Ebenezer Obey wà nínú ìbànújẹ́?

Gẹgẹ bi oloye ẹgbẹ APC Hakeem Bamgbola ṣe kede.

Inu oṣu kẹsàn-án ọdun to kọja ni wọn fi Oloto jẹ Ọba Iguru.

Oloto ku lẹni ọgọrin ọdun.

Known as a generous moneybag, Fuji singers like Maiyegun Wasiu Ayinde Marshal, Saheed Osupa, Wasiu Alabi Pasuma, Adewale Ayuba, and late Sikiru Ayinde Barrister, enjoyed from the late society figure's largesse.

5. Sound Sultan:

Ni ọjọ́ kọkanlá, 2021, ikú gbajúgbajà olórin mi gbogbo orileede Nàìjíríà tìtì lẹ́ni odun mẹ́rinlélogoji nígbà ti wọ́n kede ikú rẹ̀ Wo ohun tí TuFace, Mr Macaroni àti DJ Cuppy sọ nípa Sound Sultan .

Olanrewaju Abdul-Ganiu Fasasi tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Sound Sultan ni iroyin kan pe o ni aarun jẹjẹrẹ.

Ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ lo ṣe ẹyẹ ikẹyin fun, wọn se apejuwe rẹ gẹgẹ bi ẹni to nii aanu ọmọlakeji rẹ

6. Zainab Booth:

Gbajugbaja osere Kannywood, ẹgbẹ osere ti awọn Hausa, ni okiki kan pe oun naa papoda.

Zainab kun ni ọjọ kini osu keje, leyin aisan ranpẹ ni ilu Kano gẹgẹ bi ọmọ rẹ ṣe fi lede ni oju opo ikansiraẹni rẹ.

Ẹni ọdun mọkanlelọgọta ni Zainab Booth ki o to jade laye.

7. .Ibrahim Aliyu:

Gomina ologun ti ipinlẹ Jigawa tẹlẹ, Brigedier General Ibrahim Aliyu ku ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu keje nilu Kaduna.

Gẹgẹ bi atẹjade ti agbenusọ rẹ lori iroyin ati igbohun safẹfẹ Habibu Nuhu Kila fi sita.

Aliyu gẹ gomina Jigawa labẹ ológun lati ọjọ kẹsan-an oṣu Kejila ọdun 1993 si ọjọ kjilelogun oṣu kẹjọ odun 1996 labẹ ọgagun Sanni Abacha

8. Felix Odey ( Feladey)

Owurọ kutu ọjọ kọkandilọgbọn ni kọrinkọrin ati olootu orin Felix Odey naa jade laye.

Otutu lasan ni wọn ni o sọ pe o n pa oun ti o si jade laye.

9. Iyom Chinelo Amechi

Iyawo minisita Irina ofurufu akọkọ, Iyim Chinelo Amaechi ku ni ọjọ kẹtalelogun, oṣu keje, ọdun 2021 ni ile iwosan Nnamdi Azikiwe leyin aisan ranpẹ.

O ku ni ẹni ọdun mọkanlelaadọrin

10. Mojisola Oyefeko at 85

Olufaraji fun isẹ Ọlọrun o tun gbajumọ Mojisola Oyefeko ku ni ẹni odun marundinlaadọrun.

O jẹ okan laea awọn oludasilẹ Crusdees Society ni Yaba ninu ijọ Baptist Sabo nipinlẹ Eko