Ìròyìn òfegè ni pé Alabi Yellow jáde láyé lánàá

Ọjọ Aiku, to jẹ ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2021 ni iroyin jade pe gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Samuel Alabi Oludayo Akinpelu, ti ọpọ mọ si Alabi Yellow ti jade laye.

Bo tilẹ jẹ pe ko lootọ ni Alabi Yellow ti dagbere faye, ṣugbọn o ti to nnkan bii ọdun meji sẹyin ti Alabi Yellow ti ku.

Ọdun 2019 ni Alabi Yellow fi aye silẹ lẹni ọdun mejilelọgọta nile rẹ to wa lagbegbe Ikorodu, niluu Eko.

Ṣaaju ni iroyin iku rẹ ti kọkọ gbode kan lori ayelujara lọdun naa lọhun ki ojugba rẹ ninu iṣẹ tiata, Saidi balogun to fidi iroyin naa mulẹ.

Alabi yellow ti kọkọ n ṣaisan rọpa-rọsẹ ki ọlọjọ to de.

Lara awọn to gbe owo fun lati fi tọju ara rẹ ni gbajugba wolii obinri ijọ alaṣọ funfun, Esther Ajayi, to fi mọ awọn oṣere ẹgbẹ rẹ.

Iroyin iku rẹ ba ọpọ awọn ololufẹ rẹ lojiji nitori o ti kọkọ kopa ninu ere kan ti Kunle Afolayan gbe jade ti akọle rẹ n jẹ Mọkalik.

Fiimu Mọkalik ọhun jade loṣu Karun un, ọdun 2019, ki Alabi Yellow to fi aye silẹ.

Titi di askoko ti a n ko iroyin yoi jọ, ako le sọ eredi ti awọn eeyan kan ṣe n gbe iroyin naa kiri olooge naa ṣẹṣẹ jade laye nigba ti iṣẹlẹ naa ti waye ṣaaju ni nnkan bii ọdun meji sẹyin?