You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Pa Kasunmu: Kayode Odumosu,papòdà lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínláàdọ́rin
Gbajugbaja oṣere tiata Kayode Odumosu ti gbogbo eeyan mọ si Pa Kasumu ti dagbere faye.
Lọjọ Aiku ni aarẹ awọn oṣere tiata Yoruba Naijiria Bolaji Amusan Mr Latin fidi ọrọ naa mulẹ fun ileeṣẹ BBC Yoruba.
O ti to ọjọ mẹta ti aisan ti n ba Pa Kasunmu finra.
''Eeyan daada ni wọn yatọ si pe wọn jẹ oṣere tiata.Iku wọn jẹ eleyi to fi ọwọ kan wa lẹmi''
Yatọ si Mr Latin awọn oṣere miran bi Foluke Daramola ti fi ikede iku Pa Kasumu i oju opo wọn ni Instagram pẹlu ọrọ ikẹdun iku rẹ.
Ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹta ọdun 1953 ni wọn bi Kayode Odumosu ni ilu Ibadan.
Ọmọ Odogbolu ni ipinlẹ Ogun ni a gbọ pe Baba rẹ jẹ ti iya rẹ si jẹ ọmọ Abeokuta.
O ti kopa ninu ọpọ ere sinima ti awọn eeyan si mọ gẹgẹ bi ogbontarigi ninu awọn adẹrinposonu ere tiata lede Yoruba ati Gẹẹsi.