You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
BangladeshThunder bolts: Àrá sán pa èèyàn 17 níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó
Oriṣiiriṣii lo n ṣẹlẹ ni duniyan. O kere tan, eeyan mẹtadinlogun lo ba Ọlọrun ni alejo lẹyin ti aramọka san pa wọn.
Nibi ayẹyẹ igbeyawo lawọn eeyan naa wa lorilẹede Bangladesh ti iṣẹlẹ ọhun fi ṣẹlẹ.
Eeyan mẹrinla to fi mọ ọkọ iyawo gan an gan an lo farapa nibi iṣẹlẹ naa.
- Àrá kọ ṣàràà! Ó sán pa èèyan 16 tó ń ya "Selfie" lórí ilé gogoro
- Ẹran Akíka(Pangolin) àti ìwo Erin d'ẹ́rù b'olẹ̀, ìjọba f'òfin gba bílíọ́nù 22 ẹran ara wọn
- Àṣìṣe ńlá ni Tinubu ṣe tó ti Buhari lẹ́yìn tó fi dé ipò- Oba Shomolu-Bariga
- Dánáfojúrà nìyí, abàmì eégún tí ń gbé inú iná ṣọlá
- Wo àwòrán ìgbéyàwó ọkùnrin tó gbé obìnrin mẹ́rin níyàwó lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Òjò àrọ̀rọ̀dá gbẹ̀mí èèyàn mẹ́ta ní Oshogbo,ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò
Amọ ori ko iyawo yọ nitori ko tii wa nibẹ nigba ti iṣẹlẹ ọhun waye.
Iroyin sọ pe awọn eeyan naa n bọọlẹ lati inu ọkọ oju omi niluu Shibganj lọ si ile iyawo nigba ti ara bẹrẹ si ni san.
Awọn eeyan ilu naa ṣalaye pe oriṣiiriṣii ẹdun ara lo ba awọn eeyan naa.
Ọdọọdun ni ara maa n san pa awọn eeyan apa Guusu ilẹ Asia.
Koda, orilẹede Bangladesh kede iṣẹlẹ aramọka gẹgẹ bi ijamba fun orilẹede naa lẹyin ti ara san pa igba eeyan loṣu marun un ọdun naa.
Bakan naa, ara tun san pa eeyan mejilelọgọrin lọjọ kan ṣoṣo lasiko naa.
- ESABOD gbé ìjà Mide Martins rù sórí ara rẹ̀ ó ń fi èpè ránṣẹ́ sí Adunni Olorisa àtàwọn míì
- Kò sí olóṣèlú kankan tó ń pàṣẹ fún wa pé kí á máa ti aráálú mọ́lé- DSS
- Wo àwòrán ìgbéyàwó ọkùnrin tó gbé obìnrin mẹ́rin níyàwó lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Níbo ló kù tí Messi yóò lọ báyìí?
- Àwọn ìlúmọ̀ọ́ká Mẹ́wàá to kú nínú oṣù keje odun 2021
- "Ẹ yé fún àwọn ọkọ yín lọ́yàn mu mọ́, àwọn ọmọ ló lọyàn"
Awọn onimọ nipa oju ọjọ sọ pe bi awọn eeyan ṣe n gegi ninu igbo wa lara ohun to jẹ ki ara maa san pa awọn eeyan.
Wọn ni awọn igi to ga ninu igbo lo n maa n gba ara sara ki wọn to ge wọn lulẹ.