Ẹ wo irú itú tí Sefiu Alao pa lóríi ètò Ṣé O LÁYÀ
- Author, Emmanuel James
- Role, Video Journalist
Ori eto ṣe o laya ti BBC News Yoruba lo ti dahun awọ̀n ibeere to jẹ mọ̀ asa, iṣesi ati owe Yoruba.
Lẹyin o rẹyin ọgbẹni Alao gba pe, o di dandan ki oun lọ tun ẹkọ Yoruba kọ nítọri pe imọ oun ku díẹ kaato ninu awọn ibeere ti a bii
Adekunle Sefiu Alao gangan ni orukọ rẹ amọ Sefiu Alao ni ọpọlọpọ mọ olorin yii si.

Lagbo awọn olorin Fuji Yoruba, eekan ni Sefiu Alao jẹ ti ọpọlọpọ eeyan si fẹran awọn orin rẹ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo to ni pẹlu BBC Yoruba, Sefiu mu wa rinrinajo bo ṣe bẹrẹ ninu iṣẹ to yan laayo.
O ranti gbogbo igba to bẹrẹ orin kikọ ni kekere lasiko to ṣi wa ni ileewe girama.













