Ta ló gbé igbá fún Mama Rainbow láti ṣí wò?

Àkọlé fídíò, Ta ló gbé igbá fún Mama Rainbow láti ṣí wò?
Ta ló gbé igbá fún Mama Rainbow láti ṣí wò?

Gbajumọ oṣere tiata ti ko ni ọrọ ẹja-n-bakan ni Mama Idowu Philips ti ọpọ mọ si Mama Rainbow.

Mama Rainbow si tun jẹwọ ara wọn gẹgẹbi iya, ololufẹ aṣa ati gbigba imọ kun imọ lori eto BBC News Yoruba, “Ṣe O laya?”

Bi Mama Rainbow ti n dahun awọn ibeere ti ikọ BBC News Yoruba bi wọn naa ni wọn tun n ke si gbogbo mutumuwa lori pataki aṣa ati ede wa, paapaajulọ kikọ awọn ọmọ ki ede ati aṣa ma baa parun.

Gbajumọ oṣere ni Mama Rainbow ti o si ti kopa ninu ọpọlọpọ ere eyi to ti le ni aadọta.

Ọdun 1942 ni a bi iya Rainbow ni ilu Ijẹbu Ode ni ipinlẹ Ogun lorilẹede Naijiria. Iṣẹ ilera ni iya Rainbow fi bẹrẹ lawọn ile iwosan ijọba kan ni Naijiria. Nigba naa, iṣẹ ajamọ ni iṣẹ tiata.

Lẹyin iku ọkọ rẹ, Augaustine Ayanfẹmi Phillips, ẹni to ba agba oṣere, Hubert Ogunde ṣiṣẹ fun ọpọlọpọ ọdun, ni Mama Rainbow to wa kanlu agbami iṣẹ tiata.

ọdun 2022 ni agba oṣere naa ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọrin ọdun lori oke erupẹ.