Kí ló ṣẹlẹ̀ s’àwọn tó ń f’ọmọ ṣe kátàkárà tó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera?

L'ọdun mẹta sẹyin, iwadii BBC tu aṣiri awọn gbọmọ-gbọmọ kan to n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ eto ilera oniwa ibajẹ, ati awọn alai ni ile lori to n mu ogun oloro lorilẹede Kenya.
Ni bayii, BBC tun pada lati mọ ipa ti iṣe iwadii ti o ṣe ti ni.
Lẹyin ọjọ ti abajade iṣe iwadii BBC bọ sori afẹfẹ, ijọba ṣe ileri lati gbogun ti awọn to n lo ọmọde lọna aitọ.
Ṣugbọn lẹyin ọdun mẹta, ko si apẹrẹ imuṣẹ ileri ti ijọba ṣe.
BBC kan si ajọ to ri si eto aabo ilu ni Kenya, ṣugbọn wọn ko fesi.
Jakejado Kenya, ni ọpọlọpọ obi lo ṣi n wa awọn ọmọ wọn.












