Kí ni owó orí ọjà tí Trump ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé kalẹ̀ àti pé àwọn orílẹ̀èdè wo ló máa fara gbá a?

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Donald Trump ní okoòwò ilẹ̀ òkèrè ń ṣàkóbá fún Amẹ́ríkà
    • Author, Jeremy Howell and Onur Erem
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ìkéde Ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, Donald Trump láti máa gba owó orí lórí àwọn ọjà tí wọ́n ń kó wọ Amẹ́ríkà láti Mexico, Canada àti China ti mú kí àwọn onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé sọ pé ìgbésẹ̀ náà yóò ṣàkóbá fún ọrọ̀ ajé, tó sì lè mú kí àwọn èèyàn pàdánù iṣẹ́ wọn.

Trump kéde gbígba owó orí ìdá mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25%) lórí ọjà tó bá ń wọlé láti Canada àti Mexico àti ìdá mẹ́wàá (10%) lórí ọjà tó bá ń wọ Amẹ́ríkà láti China.

Ó ní ìgbésẹ̀ yìí yóò wà bẹ́ẹ̀ títí tí àdínkù yóò fi bá iye fentanyl tí wọ́n ń kó wọ Amẹ́ríkà àti bí àwọn ènìyàn ṣe ń wọ Amẹ́ríkà lọ́nà àìtọ́.

Bákan náà ló dúnkokò láti máa gba owó orí lórí àwọn ọjà tó bá ń wọ Amẹ́ríkà láti àwọn orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Yúróòpù.

Wọ́n ti ṣe ìdádúrò gbígba owó orí ọjà tó ń wá láti Mexico fún oṣù kan. Canada náà sì tí àwọn náà yóò máa gba owó orí lórí àwọn ọjà tó bá ń wọ orílẹ̀ èdè láti Amẹ́ríkà.

Àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn náà ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti gbé ìgbésẹ̀ tí Canada fẹ́ gbé náà.

Kí ni owó orí ọjà?

Owó orí ọjà lórí àwọn ọjà tí wọ́n ń kó wọ orílẹ̀ èdè kan láti orílẹ̀ èdè mìíràn ni wọ́n ń pè ní tariffs ní èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Iléeṣẹ́ tó bá ń kó ọjà náà wọlé ló máa san owó náà dípò orílẹ̀ èdè tó ń fi ọjà náà ránṣẹ́.

Èyí túmọ̀ sí pé tí iléeṣẹ́ kan bá fẹ́ ra ọkọ̀ tí iye rẹ̀ jẹ́ $50,000 láti ilẹ̀ òkèrè, iléeṣẹ́ náà máa san àlékún $12,500 tó jẹ́ ìdá mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n gẹ́gẹ́ bí owó orí lórí ọkọ̀ náà.

Ìbéèrè ni pé orí ta ni àlékún owó orí máa wà?

Tí iléeṣẹ́ tó ń kó ọjà wọlé bá fi owó orí kún iye tí wọ́n máa ta ọjà, ó túmọ̀ sí pé àwọn aráàlú tó bá ń ra irú ọjà bẹ́ẹ̀ ni yóò fi ara kó àlékún náà.

Kí ló dé tí Trump fi gbé owó orí lé àwọn ọjà?

Ààrẹ Donald Trump ti máa ń sọ pé fífi owó orí lé ọjà tí wọ́n ń kó wọ orílẹ̀ èdè wọn láti ilẹ̀ òkèrè yóò jẹ́ kí àwọn ọjà tí wọ́n ń pèsè lábẹ́lé ní ìgbèrú, tó sì jẹ́ ọ̀nà láti mú kí ètò ọrọ̀ ajé Amẹ́ríkà lọ sókè àti mímú owó tó ń wọlé fún ìjọba látara owó orí pọ̀ si.

"Lábẹ́ èròńgbà mi, òṣìṣẹ́ Amẹ́ríkà kankan kò ní máa bẹ̀rù pé òun yóò pàdánù iṣẹ́ òun sọ́wọ́ ilẹ̀ òkèrè bíkòṣe pé àwọn ilẹ̀ òkèrè yóò máa bẹ̀rù láti pàdánù iṣẹ́ wọn sọ́wọ́ ọmọ Amẹ́ríkà."

Trump tún sọ pé àwọn orí ọjà yìí, bíi irú èyí tó ṣe lórí alumíníọ̀mù nígbà tó wà nípò Ààrẹ lọ́dún 2018 yóò mú ètò ààbò Amẹ́ríkà rú gọ́gọ́ si.

"Wọn kìí ra ọkọ̀ wa, wọn kìí ra oúnjẹ wa, kò sí nǹkankan tí wọ́n ń mú lọ́dọ̀ wa tí àwa sì ń kó gbogbo nǹkan wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ àti oúnjẹ wọn," Trump sọ.

Owó orí ọjà wọ ni Trump gbé kalẹ̀ ní sáà àkọ́kọ́ rẹ̀?

Òṣìṣẹ́ tó ń jó irin ní California

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Òṣìṣẹ́ tó ń jó irin ní California
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ọdún 2018, Trump ṣàgbékàlẹ́ owó orí ìdá àádọ́ta (50%) lórí ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń fọ aṣọ àtàwọn ẹ̀rọ amúnáwá tó ń lo oòrùn. Ìjọba Amẹ́ríkà ní àwọn iléeṣẹ́ tó jẹ́ ọmọ Amẹ́ríkà tó ń pèsè àwọn ẹ̀rọ náà ń kojú ìdíje tó lágbára pẹ̀lú àwọn iléeṣẹ́ ti ilẹ̀ òkèrè púpọ̀ jù.

Bẹ́ẹ̀ náà ló gbé ìdá mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25%) gẹ́gẹ́ bí owó orí lé àwọn steel àti aluminum lásìkò náà.

Wọn kò fi owó orí lé àwọn steel àti aluminum tó ń wọ Amẹ́ríkà láti Mexico àti Canada nígbà náà nítorí àdéhùn títa ọjà lọ́fẹ̀ẹ́ tó wà láàárín àwọn orílẹ̀ èdè náà.

Àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yúróòpù, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó máa ń kó steel wọ Amẹ́ríkà jùlọ náà gbé ìgbésẹ̀ láti fi owó orí lé ọjà tó ń wọ orílẹ̀ èdè wọn láti US bíi aṣọ, ọ̀kadà Harley Davidson tí iye rẹ̀ tó $3bn.

Trump tún fi owó orí ọjà lé àwọn tó ń wọ Amẹ́ríkà láti China bíi ohun èlò orin àti ẹran tí iye wọn tó $360bn tí China náà sì dá a padà pẹ̀lú gbígbé owó orí lé ọjà ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí iye rẹ̀ tó $110bn.

Àwọn owó orí ọjà tó ń wọlé láti China wà bẹ́ẹ̀ lábẹ́ ìṣèjọba Joe Biden, tí wọ́n sì tún ṣe àwọn mìíràn bíi owó orí àwọn ọkọ̀ tó ń lo iná mọ̀nàmọ́ná.

Àwọn ipa wo ni owó orí ọjà tí Trump gbé kalẹ̀ lọ́dún 2018 ní lórí àwọn orílẹ̀ èdè míì?

Àwòrán tó ń ṣàfihàn bí Mexico, China àti Canada ṣe kó ọjà wọ US sí

Owó orí ọjà tí Trump gbé kalẹ̀ nígbà náà jẹ́ kí àdínkù bá iye ọjà tí wọ́n ń kó wọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà láti àwọn orílẹ̀ èdè kan, tó sì mú àlékún bá iye ọjà tí wọ́n ń kó wọlé ní orílẹ̀ èdè mìíràn.

Ṣáájú 2018, ọjà tó máa ń wọ Amẹ́ríkà láti China jẹ́ ìdá méjìlélógún (22%). Ní ọdún 2024 ìdá mẹ́tàlá àti àbọ̀ (13.5%) ni iye ọjà tó wọ Amẹ́ríkà láti China gẹ́gẹ́ bí àjọ US Census Bureau ṣe sọ.

Mexico gba ipò orílẹ̀ èdè China lọ́dún 2023 bíi orílẹ̀ èdè tó ń kó ọjà wọ Amẹ́ríkà jùlọ pẹ̀lú kíkó ọjà tí iye tó $476bn wọ US.

Òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ VW ní Mexico

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Mexico ni wọ́n ti ń pèsè ọkọ̀ jùlọ

Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ pàápàá àwọn tó ń pèsè ọkọ̀ ló gbé iléeṣẹ́ wọn lọ sí Mexico láti jẹ àǹfàní ètò ọjà ọ̀fẹ́ tó wà láàárín Amẹ́ríkà àti Mexico.

Bákan náà ni àwọn orílẹ̀ èdè tó wà ní ìlà oòrùn Asia náà rí ọjà kó wọ Amẹ́ríkà.

Gẹ́gẹ́ bí àkọ́ọ́lẹ̀ US Trade Representative ṣe sọ, Indonesia, Philippines, Thailand àti Vietnam ni àlékún bá iye ọjà tí wọ́n kó wọ US lọ́dún 2023.

Àwòrán bí China àti àwọn orílẹ̀ èdè Asia míì ṣe kó ọjà wọ US
Àkọlé àwòrán, Àwòrán bí China àti àwọn orílẹ̀ èdè Asia míì ṣe kó ọjà wọ US

Dókítà Nicolo Tamberi, onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Sussex, UK sọ pé China ni ṣíṣe àgbékalẹ̀ owó orí ọjà Amẹ́ríkà lọ́dún 2018 ṣàkóbá fún jùlọ.

Ó ní Vietnam ló jẹ àǹfàní rẹ̀ jùlọ.

Fún US, owó orí ọjà lórí steel àti aluminum mú ìgbèrú bá ìpèsè wọn lábẹ́lé àmọ́ tó ṣokùnfà kí owó àwọn ọjà náà gbẹ́nu sókè.

Àjọ Peterson Institute for International Economics sọ pé àwọn ìgbésẹ̀ fífi owó orí lé ọjà ń mú kí owó ọjà lọ sókè si.

Owó orí ọjà wo ni Trump ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe?

Àwọn èèyàn tó fẹ́ wọ Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Trump ti gbé ìdá mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25%) lé orí àwọn ọjà tí yóò máa wọ Amẹ́ríkà láti Mexico àti Canada àyàfi epo rọ̀bì tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá (10%) láti Canada. Ìdá mẹ́wàá (10%) ló tún fi lé ọjà tí yóò máa wọ orílẹ̀ èdè náà láti China yàtọ̀ sí àwọn èyí tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Ní ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kejì ni ti China àti China yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní wá sí ìmúṣẹ, tí ti Mexico yóò sì bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn oṣù kan.

Canada náà ti bẹ̀rẹ̀ fífi ìdá mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25%) kún owó orí ọjà tó bá ń wọ orílẹ̀ èdè wọn láti Amẹ́ríkà tó fi mọ́ ọtí àtàwọn ohun èlò ilé.

Mexico àti Canada náà ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ti wọn náà.

Báwo ni owó orí ọjà yóò ṣe ní ìpalára lórí Canada àti Mexico?

Àwọn tó ń wá iṣẹ́ ní Mexico

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Owó orí ọjà le gba iṣẹ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ní Mexico

Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Stephen Millard ti àjọ National Institute of Economic and Social Research ní UK ṣe sọ, owó orí ọjà náà yóò kóbá ọrọ̀ ajé Canada àti Mexico tó bá pẹ́.

Àwọn orílẹ̀ èdè méjèèjì gbára lé ọjà tí wọ́n máa ń rà láti Amẹ́ríkà púpọ̀. Ìdá mẹ́tàlélọ́gọ́rin (83%) ọjà tí Mexico ń ta ló ń wá láti ilẹ̀ òkèrè.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Millard ní Amẹ́ríkà ni Canada ń ta ọ̀pọ̀ epo rọ̀bì rẹ̀ fún àti pé àlékún owó ọjà náà yóò mú àdínkù bá iye tí wọ́n pa wọlé lọ́dún.

Lila Abed láti àjọ Wilson Centre, Mexico sọ pé owó orí ọjà náà yóò ní ipa lórí àwọn òṣìṣẹ́ Mexico nítorí èèyàn mílíọ̀nù márùn-ún ni iṣẹ́ wọn dá lórí okoòwò tó ń wáyé láàárín Amẹ́ríkà àti Mexico.