Gbajúmọ̀ akọrin, Portable ko ìjàmbá ọkọ́, wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí G-Wagon rẹ̀

Aworan ọkọ naa ti Portable

Oríṣun àwòrán, von

Ori ko Gbajumọ Olorin takasufe, Habeeb Olawunmi ti ọpọ mọ si Portable yọ ninu ijamba ọkọ.

Portable fi oko ayọkẹlẹ G-wagon rẹ kagbako ijamba mọto ni agbegbe Osapa London, Lekki nipinlẹ Eko lọjọru.

Gbajumọ olorin Zazu zeh naa n wa ọkọ ọhun lọ si agbegbe ile orin rẹ ninu arọrọda ojo to waye lasiko ti ijamba naa fi waye.

Aworan ti gbajumọ olorin naa fi sori ayelujara fihan pe nṣe bi ọkọ ayọkẹlẹ olowo iyebiye G-Wagon naa se bajẹ kọja ala .

“Iṣẹ aṣekara ti mo ṣe ra ọkọ yii yoo tun ra omiran.

“Ẹ ko le ba aye mi jẹ. Mo ra ọkọ, wọn fi ẹnu ba a jẹ. Ọkọ naa ko pa mi.”

‘Wọn ni owo ẹjẹ ni mo fi ra ọkọ mi’

Portable

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ni oṣu karun un ọdun 2023 ni Portable kede pe oun ra ọkọ ji wagon. Oniruuru awuyewuye lo waye nigba naa lori bi o se ri owo ọkọ ọhun.

‘Were olorin’ naa, gẹgẹ bi Portable ṣe maa n ki ara rẹ ṣalaye siwaju ninu fidio to fi sita naa pe oun ko ṣẹṣo rara bi awọn kan ṣe n ro.

“Wọn ni mo ṣe ogun owo ati pe yoo gbẹmi mi. Arọrọda ojo lo fa a, mo n lọ si ileeṣẹ orin mi ni nigba ti ijamba naa ṣẹlẹ.

“Ko si iku kan to le pa mi, mo ti ṣe ogun, ẹ ko lee ri mi.”