Obìnrin tó wọ ọkọ̀ 'Uber' yìnbọn lu dẹrẹbà tórí ó rò pé àjínigbé ni

Obinrin to pa Dẹrẹba

Oríṣun àwòrán, El Paso Police Department

Wọn ti fi ẹsun ipaniyan kan arabinrin kan lẹ́yìn to yinbọn pa awakọ Ileeṣẹ Uber kan to ni oun ro pe o fẹ ji oun gbé ní ní Amẹrika, Ọlọpaa sọ bẹẹ.

Gẹgẹ bi awọn ikọ Ọlọpaa to wa ni ilu El Paso, Texas ṣe sọ, arabinrin ọhun, Phoebe Copas gbagbọ pe o n gbe oun lọ si ilu Mexico.

Lo ba fa ibọn yọ to si yin in lu direba to n wa ọkọ, Daniel Piedra Garcia. Awọn Aláṣẹ Texas fi aridaju eyi han ninu atẹjade ti wọn fi sita.

Dirẹba naa to jẹ ẹni ọdun mejilelaadọta ku si ileewosan lẹyin ọpọlọpọ ọjọ to lo pẹlu iranlọwọ ẹ̀rọ fun èémí.

Bó ṣe wa ninu ọkọ ọhun, Copas ri àmì ina to n dari ìgbòkègbodò ọkọ to n tọka si agbegbe Juarez ni Mexico, gẹgẹ bo ṣe wa ninu àkọsílẹ̀ lọdọ Ọlọpaa, ilu mejeji fi ẹgbẹ́kẹgbẹ́ ni ibode to pa US ati Mexico pọ.

Bakan naa àkọsílẹ̀ awọn Ọlọpaa fihan pe lẹyin ti o ro pe awakọ naa fẹ ji oun gbé ni, Copas yọ ibọn jade ninu baagi rẹ o si yìn ín ba direba naa lori. Bẹẹ si ni ọkọ naa kọlu awọn nnkan to wa loju pópó ko to di pe o duro.

Kentucky ni arabinrin Copas ti n bọ amọ o fẹ lọ ṣe abẹwo si ọrẹkunrin rẹ. Wọn fi ẹsun kan an pe o pe nọ́mbà Ọlọpaa o si ya foto awakọ naa o tún fi ránṣẹ́ sí ọrẹkunrin rẹ.

Ẹwẹ, iwadii to n lọ lọwọ ko fi ẹsẹ rẹ múlẹ̀ boya ijinigbe kankan waye tabi pe Piedra dojú wíwa ọkọ kọ ọna ibi ti Copas n lọ, atẹjade Ileeṣẹ Ọlọpaa El Paso sọ eyi.