Sit-at-home: Ìgboro Enugu, Abia dá páropáro lásìkò òfin kóní-ó- gbélé tó máa ń wáyé ní ọjọọjọ́ Ajé

Awọn ile itaja, ọna ati ọja da paroparo ni ọjọ Aje ni ipinlẹ Enugu ati awọn ipinlẹ miran ni iha guusu-ila oorun, orilẹede Naijiria.
Eyi ko ṣẹyin bi awọn araalu se joko si ile wọn lati tẹle aṣẹ ti adari ẹgbe awọn to n ja fun ominira ilẹ Biafra pe, iyẹn IPOB.
Bakan naa ni o se ri ni ipinlẹ Abia to jẹ ipinlẹ miran ni iha naa, ti gbogbo ọna si da paroparo, ti ko tilẹ si ẹnikẹni to rin lasiko naa.
Eyi n waye lẹyin ti adari ikọ IPOB, Nnamdi Kanu Nnamdi Kanu to w ani atimọle paṣẹ fun Simon Ekpa to w ani Finland to si n ja fun ẹtọ IPOB, lati fi opin si aṣẹ ki onile-gbele.
Lati ọdun 2021 ni Ekpa ti n paṣẹ ki awọn eniyan joko si ile wọn titi ijọba yoo fi fi Kanu silẹ lori ẹsun iditẹgbajọba ti ijọba apapọ fi kan an
Ẹ ma se atako si awọn gomina tabi oloselu – Nnamdi Kanu
Kanu to wa ni ati mọle nipasẹ awọn agbẹjoro rẹ, Aloy Ejimakor to soju wọn fi lẹta ranṣẹ si Ekpa pe ki o jawọ ki awọn eniyan joko si ile.
Aṣẹ ni eleyii, pe ki o jawọ ninu aṣẹ ki onile o gbe ni ọjoọjọ Aje.
Lẹta naa tun paṣẹ fun Ekpa ki o ye se atako si awọn gomina ati awọn oloselu nitori ko ni oye ohun ti wọn se nipasẹ rẹ.
Amọ Ekpa ni ko si otitọ ninu lẹta naa, to si da oun loju pe Kanu kọ lo kọ ọ.
Bakan naa lo paṣẹ pe ofin konile o gbele naa yoo tẹsiwaju ni Ọjọ Aje.
Kini ijọba sọ lori ofin konile-o gbele ti IPOB

Gomina ipinlẹ Enugu, Peter Mbah pasẹ fun awọn ileeṣẹ to n tẹlẹ aṣẹ naa lati ko igba wole nitori wọn n tẹlẹ aṣ̣ Simon Ekpa.
Eyi lo mu ki wọn ti awọn ile itaja to le ni ọgọrun un to n tẹlẹ asẹ naa to tako aṣẹ gomina ipinlẹ naa.
Awọn gomina naa ni aṣẹ naa tib a eto ọrọ aje jẹ ni agbegbe naa, ti awọn miran si ti sọ ẹmi wọn nu nitori awọn agbebọn to n paṣẹ fun wọn lati joko si ile wọn.
Awọn gomina ni agbegbe naa ni ọpọlọpọ triliọnu naira ni wọn n padanu ni igba de igba lati ọ̀un 2021 ti aṣẹ naa ti gberasọ.
Bakan naa ni awọn alẹnulọrọ kesi awọn gomina ati ijọba apapọ lati sisẹpọ pẹlu ijọba Finland, ki wọn le da Ekpa pada wa si ile lati wa foju wina ofin.












