NLC Protest: Jànduku ya bo àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn nílé Míńísítà fún ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́

Ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ níbi ifẹhonu han ti àwọn ẹgbẹ́ òsìṣẹ́ pinu láti gùnlé lóni ọjọrú lòdi si mínísítà fún ọ̀rọ̀ òsìsẹ́, Dokita Chris Ngige.
Wọn ṣe eyi nítori wọn fẹsun pe o kọ láti ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ adójutòfò ohun amuludun àti ikowojọ kó si fi Frank Kokori, alaga nigba ti àwọn jànduku yabo awọn afẹhonuhan nile Minisita to wa ni Asokoro ṣe alaga.
Awọn to farapa níbí iṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọn ti ko lọ si ile iwosan ǹla ti Abuja láti gba itọju. Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fi ẹsun kan mínisita pé ó n yan àwọn jánduku láti máa koju ija si awọn osisẹ.
Ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìsẹ́ Ayuba Wabba, se àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà bi èyí ti kò ba oju mu rárá.

Oríṣun àwòrán, NLC
O ni ìṣẹ̀lẹ̀ to wáye lónii kìí ṣe èyí to ba oju mú níbi ti wọn ti n fi ipá mu òṣìṣẹ́ pẹ̀lu ìbọn, to si jẹ pe àwọn oṣiṣẹ́ lọ si ile minisita lái mu ohun ija kankan dáni.
"Wọn gbe ohun ija dáni, bi mo ṣe ń baa yín sọ̀rọ̀ yìí, ènìyàn mẹ́rin lo wa ni ile ìwòsàn yàtọ si àwọn ti ibọn ba"
" Ó di dandan, à ó gbe ìgbésẹ̀ to nipọn, kàkà ki wọn dá ààbò bò wá, òun ṣe lòdi si wa. Kò si ǹkan ti a le jọ maa jòkó sọ lábẹ ]akóso boti wu kó ri, àyàfi ki ààrẹ orilẹ̀-èdè ó dá sii, láì jẹ bẹ́ẹ̀ àwọn osiṣẹ́ yóò daṣẹ́ sílẹ̀"









