UNGA: Tijjani Bande jẹ́ àgbà ọ̀jẹ̀ nípa ìbásepọ̀ àwọn orílẹ̀èdè

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Tijjani Bande to jẹ ọjọgbọn ati adari ile iwe giga Usman Dan Fodio ni ipinlẹ Sokoto ni wọn ti yan gẹgẹ bi aarẹ ẹka Ajọ Agbaye United Nations General Assembly (UNGA).
Ẹka UNGA lo wa fun ijiroro lori igbesẹ ti ajọ UN ba fẹ gbe. Adari ẹka UNGA ti o n fi ipo silẹ, María Fernanda Espinosa Garcés lo fi eyi lede lasiko to n se ipade ijiroro pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ni ilu Abuja.
María Fernanda Espinosa Garcés ni gẹrẹ ti oun ba n kuro ni ipo ni wọn yoo maa bura wọle fun Bande.
Tijjani Bande ni yoo jẹ ọmọ Naijiria keji ti yoo je aarẹ Ajọ UNGA lagbaye. Joseph Nanven Garba ni ẹni akọkọ lati Naijiria, to wa nipo naa laaarin ọdun 1989 si 1990.
Kini awọn ohun to yẹ ko o mọ nipa Àarẹ UNGA tuntun?
- Gẹgẹ bi itan nipa igbesi aye Bande ti Àjọ Isọkan Agbaye(UN) fi lede, Ọjọgbọn Bande jẹ ẹni ti o nimọ pupo nipa eto oselu lagbaye ati ibasepo laaarin awọn orilẹede.
- Tijjani Muhammad-Bande to jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgọta ni wọn bi ọdun Ọjọ Keje, Osu Kejila, ọdun 1957 ni ilu Zagga, ipinlẹ Kebbi ni ariwa orilẹede Naijiria.
- Ile iwe Ahmadu Bello lo ti lo ile -iwe giga fasiti ni ọdun 1979 to si kẹkọ gboye onimọ nipa eto oselu.
- Ọdun 1981 lo kẹkọ gboye imọ dokita ni eto oselu ni imọ eto oselu lati ile-iwe giga fasiti Boston ati ile -iwe fasiti Toronto ni orilẹede Canada ni ọdun 1987.
- O sisẹ gẹgẹ bi adari ẹka Le Centre Africain de Formation et de Recherche Administratives pour le Dèveloppement (CAFRAD) to wa fun idagbasoke ilẹ Afirika laaarin ọdun 2000 si ọdun 2004 ni ilẹ Morocco.
- Ọdun 2010 si 2016 lo wọn fi jẹ adari ajọ eto ẹkọ ni ẹka ‘National Institute for Policy and Strategic Studies’ lorilẹede Naijiria.
- Lasiko to sisẹ gẹgẹ bi asoju orilẹede Naijiria ni ọdun 2018 si 2019, Ajọ UN sọ wi pe ọjọgbọn Bande naa sisẹ karakara, ti o si ni ibasepọ to dan mọran laarin oun ati awọn osisẹ aj naa lagbaye.
- Bakan naa, Ọjọgbọn Bande ti gba oye ọlọla to gaju lọ lorilẹede Naijiria gẹgẹ bi ara ilu, iyẹn ‘Officer of the Order of the Federal Republic (OFR)’.








