National Assembly:Nkán mẹ́rin tí yóò ṣatọna àwọn tí yóò jẹ́ olórí ilé aṣòfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, @NGRSENATE
Iwe eri iyansipo ti awọn asọfin gba lọwọ ajọ eleto idibo Naijiria lọ́jọ Kerinla Oṣu Kẹta ti ṣina fun idunadura awọn ti yoo ṣakoso ile asofin orileede Naijiria.
Nigba ti a o ba fi ri oṣu Kẹfa ọdun yii, wọn yoo ṣe ifilọlẹ awọn asofin tuntun fun saa kẹsan ile asofin Naijiria.
Bi ipalẹmọ naa ti ṣe n sunmọ dẹdẹ ibeere kan to gbẹnu awọn awoye ati pupọ ọmọ Naijiria ni ẹni ti yoo dipo aarẹ ile asofin agba ati ti olori ile asojusofin mu.
Agbodegba ẹgbẹ oṣelu APC Ogbẹni Lanre Issa Onilu lai pẹ yi s pe ẹgbẹ awọn ko ni tẹri sinu aṣiṣe iru e;eyi ti o ṣẹlẹ lọdun 2015.Fun idi eleyi,o ni awọn yoo ri pe ẹni ti yoo di awọn ipo yi mu gbọdọ jẹ ẹni ti yoo ṣiṣẹ pẹlu aarẹ lati mu erongba ẹgbẹ ṣẹ.
Lara awọn idi ti yoo satọna ẹni ti yoo di ipo yi mu ni a fẹ gbiyanju lati yanana fun yin.
''Zoning''
Ẹgbẹ oṣelu to wa lori oye ni awọn yoo pin ipo awọn ti yoo ṣakoso ile laarin awọn ẹkunjẹkun orileede Naijira ni.
Gẹgẹ bi ọgbẹni Lanre Issa Onilu ti ṣe sọ, o ni awọn yoo gbe igbeṣẹ naa lati jẹki awọn eeyan ẹkun naa laanfaani lati dije fun ipo ohun.
O tun salaye pe awọn asiwaju ẹgbẹ yoo ṣe ipade laipe lati le ṣe agbekalẹ ilana ti yoo tọ awọn aṣofin ti igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ naa yoo si ṣe ipade lori igbesẹ naa.
Iye ọdun ti eeyan lo ati iriri rẹ nipa ile aṣofin
Awọn ti yoo ri ipo to munadoko di mu ni ile aṣofin kẹsan yi yoo jẹ awọn ti wn jẹ odu nile asofin.
Ohun ti eleyi tunmọ si ni wi pe awọn aṣofin to n bọ wa si ile fun igba akọkọ ko ni laanfaani lati ri awọn ipo yi dimu.
Awọn to ti pẹ ati awọn Gomina to n bọwa si ile asofin yoo wa lara awọn ti o ṣeeṣe ki wọn di ipo pataki mu nile.
Awọn to ni akọsilẹ daada ti wọn ti gbe ṣe
Ki eeyan to le ni ohun yoo di ipo pataki mu nile aṣofin, o gbọdọ jẹ ẹni ti o ni akọsilẹ daada ti awọn eeyan si n sọ ọrọ rẹ daada.
Ita Enang to jẹ oluranlọwọ agba fun aarẹ lori ọrọ ile asofin Naijiria ni aṣofin kankan ti awujọ ko ba fi oju rere wo ko ni ri ipo pataki dimu nile aṣofin.
Eni to ba ni ibaṣepọ daada pẹlu awọn aṣofin akẹgbẹ rẹ
Ohun pataki miran ti yoo ṣe atọna boya eeyan yoo di ipo pataki mu nile asofin ni bi o ba ti ṣe ni ibaṣepọ pẹlu awọn aṣofin akẹgbẹ rẹ.
Ita Enang ni ọrọ ki ṣe ohun amuṣere rara nitori pe ẹni ti ko ba duro daada laarin yi ko nidipo pataki kankan mu.
O ni ẹgbẹ oṣelu awọn yoo fọrọwerọ pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn ko ni ọmọ ẹgbẹ pupọ nile lati ri wi pe ero wọn papọ pẹlu ti aarẹ.
O ni eyi se pataki lati jẹ ki awọn eto ijọba di mimuṣẹ fun anfaani gbogbo eeyan Naijiria.












