Ọlọ́páà Ghana ń wa pásítọ̀ tó fẹsẹ̀ fẹ lẹ́yìn tọ́mọ ijọ rì sọ́mi

ODO

Oríṣun àwòrán, DONAT SOROKIN

Àkọlé àwòrán, Pásítọ̀ fẹsẹ̀ fẹ lẹ́yìn tọ́mọ ijọ rì sọ́mi

Ẹni ọmọ ogún ọdún kan kú ikú oró ní orílẹ̀-èdè Ghana, lẹ́yìn tó rì sínú omi lásìkò tó lọ se ìrìbọmi ní odò Densu, ní Accra.

Akoroyin BBC ní Ghana Favour Nunoo tó ba agbenusọ ọlọpàá ní Accra DSP Afia Tenge tó fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ sàlàyé pé ní gẹ́rẹ́ ti àwọn gbọ́ ìṣẹ́lẹ̀ náà ní àwọn lọ sí ibi tó ti sẹlẹ̀ ti ọ̀kan nínú àwọn olùsọ́àgùntàn ìjọ náà ti wà ní gbaga ọlọ́pàá báyìí.

Nínú fọ́nrán tó ń jà ràìnràìn lọ́ri ayélujárá ní Accra, ọdámọkunrin tó dórú sétí odò àti olùsọ́àgùntàn tó ń rìí bọ inú odò ní àkọ́kọ́, ìrìbọmi elékejì ní okùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí ni rì.

Ẹ wo fọrán ìrìbọmi náà ní àtagbà Ghana in Africa Facebook

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáye lọ́jọ́ àìkú, ọjọ́ kẹsán, Oṣù kejìlá, 2018, èyí tó fàá kí àwọn ìbérè máà jẹ̀yọ lórí ẹ̀rọ ayélujára pé kíló dé tí ènìyàn yóò ṣe máa sọ ẹmi rẹ̀nù nítorí ètò ẹ̀sín

Àwọn ebí eni tó kú náà sàlàyé pé kò sí ǹkan tí àwọn fẹ́ bá ọlọ́run fà àwọn kò sì da ẹbi ru ẹníkẹ́ni nínú ìṣẹlẹ̀ náà, wọ́n ní ohun tó ṣe pàtàkì ọ̀nà tí wọn ó gba sin òkú rẹ̀ ló jẹwọn lógún jùlọ.

Àjọ ọlọ́pàá tún sàlàyé fún àkọròyìn BBC pé àwọn ti rí òkú ọkùnrin nàà tí ó sì ti wà ní mọ́ṣúàrí ọlọ́pàá àti pé àwọn ó tún ṣe àyèwò okú náà kí wọn to le gbée fún àwọn ẹbi rẹ̀

Ẹ̀wẹ̀, pásítọ̀ kan tí ọwọ́ to wà ní àgọ́ wọn, nígbà ti wọn sì ń wá olórí ìjọ tó ṣe ìtẹ̀bọmi náà fún ẹni tó di olóògbé.