ASUP: Ìjọba kò sàmúsẹ àdéhùn 2009 àti 2017 la se ń wosẹ́ níran

Ile ẹkọ gbogboniṣe
Àkọlé àwòrán, ASUP Strike: Gbogbo ilé ìwé gbogbonìsẹ di títì pa

Àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ nílé ìlé ẹ̀kọ́ gbogboniṣe ìjọba tí a mọ sí (ASUP) lọjọ́ Kejìlá oṣù Kejìlá ti gùnlé ìyanṣẹ́lódi jákèjádò Nàìjíríà títí dí ọ̀jọ́ ti ìbéèrè wọn bá tó ni ìdáhùn.

Olóri ẹgbẹ́ ASUP, Usman Dutse tó bá BBC sọ̀rọ̀ sàlàyé pé, ìyàṣẹ́lódì yìí wáye nitori etí ọ̀gbọin tí ìjọba àpapọ̀ kọ sí ṣíṣe àmúlò àdéhùn ọdún 2009 àti 2017 tí wọ́n bá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ṣe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, ASUU Strike: Bí àwọn kan se dunnú, làwọn kan fajúro

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ASUU fẹnukò láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì yìí, léyìn ìpàdé àwọn ìgbìmọ aláṣẹ ẹlẹ́kẹtàléláàdọ́rún rẹ̀ tó wáyé ní ọjọ́ kọkàndílọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún yìí.

Dutse sàlàyé pé, ẹgbẹ́ nírètí pé gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ pátápátá láwọn ilé ẹkọ́ ìjọba jákèjádò orilẹede yii ni yóò kópa nínú ìyanṣẹ́lódì náà.

Tẹ ò bá gbàgbé, ìyáṣẹ́lódì yìí tún ti kún àwọn ẹgbẹ olùkọ́ ti Fasiti tó gùnlé ìyanṣẹ́lódi láti ọjọ́ kíní oṣù kọkànla.