Ngige: A ti gbà pé ìjọba yóò pèsè owónàá tó yẹ fáwọn fásitì

Oríṣun àwòrán, @SenChrisNgige
Ijọba apapọ ati ẹgbẹ awọn olukọ fasiti lorilẹ ede Naijiria, ti fẹnu ọrọ jona lori awọn ọrọ kan to se koko lẹka eto ẹkọ orilẹ ede yii.
Minisita fọrọ osisẹ ati igbanisisẹ, Chris Ngige lo kede ọrọ yii lẹyin ipade rẹ ati ẹgbẹ ASUU, eyi tijọba fi n wa ọna abayọ si iyansẹlodi tẹgbẹ naa gunle.
Ninu alaye rẹ, Ngige ni ẹgbẹ ASUU ti fun Olusiro owo agba ni apapọ iye ti adinku owo osu awọn olukọ fasiti jẹ, , ti ayẹwo yoo si bẹr lori rẹ laipẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
"A tun sọrọ nipa akoso awọn fasiti to jẹ tawọn ijọba ipinlẹ, taa si pinnu pe o yẹ ki ijọba maa pese owona fawọn ile ẹkọ fasiti, lọna ati dena ipese awọn akẹkọ ti ko muna doko lawujọ."
Nitori idi eyi, Ngige ni ileesẹ eto ẹ́kọ yoo sa agbekalẹ igbimọ kan eyi ti yoo pe akiyesi igbimọ awọn gomina sawọn isẹlẹ nipa awọn fasiti to jẹ ti wọn.
O fikun pe pẹlu ibi ti ASUU ati ijọba ba ijiroro wọn de yii, ireti wa pe ẹgbẹ ASUU yoo fi opin si iyansẹlodi wọn titi ọjọ Aje to n bọ.









